Ọọni Ogunwusi gbalejo ero rẹpẹtẹ nibi Ọdun Ọlọjọ n’Ileefẹ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ẹsẹ ko gbero niluu Ileefẹ, nipinlẹ Ọṣun, bẹẹ ni  Ile Oodua kun fọfọ lọjọ Abamẹta, Satide, ti ero si n wọ bii omi lati ba Ọọniriṣa, Ọba Ẹnitan Ọgunwusi ṣayẹyẹ Ọdun Ọlọjọ ti asekagba rẹ waye lọjọ naa.

Lati nnkan bii aago mẹwaa aarọ ni gbagede aafin, nibi ti eto Ọdun Ọlọjọ ti ọdun yii ti waye ti n kun fun oniruuru awọn eeyan ti wọn wa sibẹ, pẹlu oriṣiiriṣii aṣọ to yaayi lọrun wọn.

Aago meji ọsan ṣe ku diẹ ni kabiesi wa si gbagede igbalejo pẹlu Olori rẹ, Silẹkunọla Ogunwusi. Lara awọn ti wọn tun ba kabiesi kọwọọrin ni Igbakeji gomina ipinlẹ Kogi, Igbakeji gomina ipinlẹ Ondo, Oludasilẹ iwe iroyin Alaroye, Ọgbẹni Alao Adedayọ, Ọnarebu Rotimi Makinde ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Lẹyin ti gbogbo awọn oloye Ile Oodua nisọri-nisọri ki Ọọni tan ni awọn akẹkọ Fasiti Ifẹ ṣapẹẹrẹ awọn olori mẹrinlelogun to wa nilẹ Oodua, awọn bii Yemọja, Ṣango, Ọbatala, Eṣu, Ọṣun, Ogun ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Gbogbo awọn lẹgbẹlẹgbẹ ti wọn wale fun ayẹyẹ ọdun naa ni wọn lọọ ki kabiesi, ti ọba si ṣadura aṣọdunmọdun fun gbogbo wọn.

Gomina ipinlẹ Ọṣun, Alhaji Gboyega Oyetọla, ṣeleri nibi eto naa pe laipẹ yii ni iṣẹ yoo bẹrẹ lori ibudo ti yoo wa fun kiko awọn nnkan isẹmbaye iran Yoruba pamọ si nipinlẹ Ọṣun.

Nibi ayẹyẹ ọdun Ọlọjọ ti ọdun yii ni gomina, ẹni ti Igbakeji rẹ, Benedict Alabi, ṣoju fun, ti sọrọ idaniloju naa.

Ṣaaju ni ọdun naa ti kọkọ bẹrẹ pẹlu bi Ọọni Ogunwusi ṣe wọ Ilofi lọjọ Aikuto kọja, nibi to ti lọọ ba awọn alalẹ sọrọ nipa orileede Naijiria ati iran Yoruba lapapọ, to si jade lọjọ Ẹti, Furaidee.

Ninu ọrọ rẹ, Gomina Oyetọla ṣalaye pe pataki ni ayajọ ọdun ọlọjọ ti ọdun yii pẹlu bo ṣe papọ mọ ayajọ ọgbọn ọdun ti wọn ṣedasilẹ ipinlẹ Ọṣun.

O ni ijọba oun ko fi ọwọ kekere mu ọrọ aṣa atawọn ibudo iṣẹmbaye rara, gẹgẹ bi oun si ti ṣeleri lọdun to kọja, awọn alaṣẹ Fasiti OAU ti fi gbogbo iwe to jẹ mọ ilẹ (land) tijọba yoo lo fun kikọ ibudo naa le oun (igbakejo gomina) lọwọ.

O sọ siwaju pe gbogbo nnkan ti yoo maa daabo bo awọn nnkan isẹmbaye iran Yoruba nijọba oun yoo maa ṣe, bẹẹ loun si nigbagbọ pe owo to n wọle labẹnu funjọba le gbẹnu soke si i ti abojuto to peye ba wa fun awọn ibudo aṣa ti Eledua fi jinki ipinlẹ Ọṣun.

Lara awọn ti wọn tun wa nibi eto naa ni Ọnarebu Taofeek Ajilesoro, Oloye Dele Mọmọdu, Iyalaje Oodua, Oloye Toyin Kọlade, Kọmiṣanna fun ọrọ aṣa nipinlẹ Ọṣun, Dokita Ọbawale, Oloye Akin Ọṣuntokun atawọn eekan mi-in nidii eto aṣa ilẹ Yoruba.

Leave a Reply