Faith Adebọla
‘Ki lẹ n ṣe tẹẹ fi pọ to wọnyi, iyawo la n gbe o,’ orin ti wọn n kọ laafin Adimula Ileefẹ, Ọọniriṣa, Ọba Adeyẹyẹ Ẹniitan Ogunwusi ree nigba ti ayẹyẹ igbeyawo tuntun mi-in tun waye lopin ọsẹ yii, ti olori si n di pupọ laafin.
Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹwaa yii ni ayẹyẹ igbeyawo tuntun yii waye, nigba ti adumaadan orekelẹwa Afọlaṣade Ashley Adegoke di ayaba tuntun.
Ile awọn ana ọba tuntun naa to wa l’Opopona Olubọsẹ, lọna Ẹdẹ, niluu Ile-Ifẹ, layẹyẹ naa ti bẹrẹ, lẹyin ti wọn si ti pari gbogbo eto ifọmọfọkọ ati aṣa igbeyawo nibẹ tan ni ariya bẹrẹ ni pẹrẹwu, ẹyin naa ni wọn ko pọṣinṣinṣin ọhun tẹle Olori tuntun, ti ayẹyẹ naa si tẹsiwaju laafin Ogunwusi.
Igbeyawo ọjọ naa minringindin, ayaba fẹsẹ rajo ninu aṣọ igbeyawo funfun kinniwin to wọ:
Pẹlu igbeyawo yii, aafin Ọọni Ileefẹ ti tun rugọgọ si i, olori si tun lekan si i. Tẹ ẹ o ba gbagbe, ibẹrẹ oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, ni Mariam Anako to jẹ ọmọ bibi Ẹbira, nipinlẹ Kogi, wọle tilu-tifọn, oun lo si jokoo ti kabiesi lasiko ayajọ ọdun Ọlọjọ ti wọn ṣe kọja niluu Ileefẹ.
Bakan naa la gbọ pe laarin oṣu to kọja si oṣu yii, awọn mọlẹbi kabiesi ti lọọ tọrọ Elizabeth Ọpẹoluwa Akinmuda ati Oluwatobilọba Abigail Philipps, lọwọ awọn mọlẹbi wọn, ti ireti si wa pe awọn naa yoo daṣe wọ aafin laipẹ ti wọn yoo si di ayaba tuntun.
Gbogbo ọmọ Yoruba lo n ki Kabiesi kuu aṣeyẹ, wọn lẹṣin ọba yoo jẹko pe, olori aa ṣiṣẹ ibi, ilu yoo si tuba tuṣẹ lasiko tiwọn.