Ọọni ti sọrọ: Ipaniyan to waye ni Mọdakẹkẹ ki i ṣe ogun rara, iṣẹ ọwọ awọn amookunṣika ni

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, Ọọni ti Ileefẹ, ti sọ pe ko si ootọ ninu ahesọ kan to n lọ kaakiri pe wahala ogun Mọdakẹkẹ ati Ifẹ lo tun n kora jọ latari iṣẹlẹ iṣekupani to waye lọna abule Toro, nidaji ọjọ Ẹti, Furaidee.

Ninu atẹjade kan ti akọwe iroyin fun Ọọni, Moses Ọlafare, fi sita lo ti sọ pe iṣẹ ọwọ awọn amookunṣika kan ti aṣiri wọn ko ni pẹ ẹ tu ni iṣẹlẹ naa, nibi ti wọn ti pa agbẹ marun-un ti wọn n lọ si oko wọn.

Ọba Ogunwusi ṣalaye pe ni kete ti oun gbọ nipa iṣẹlẹ buburu naa loun ti fi to awọn agbofinro leti, ti wọn si bẹrẹ iṣẹ loju-ẹsẹ.

O ni gbogbo orileede agbaye lo n koju wahala eto aabo lọwọlọwọ bayii, o si nilo ki gbogbo araalu fọwọsowọpọ pẹlu ijọba lati le ṣẹgun rẹ.

O fi kun ọrọ rẹ pe bi awọn kan ṣe n gbiyanju lati so okun iṣẹlẹ naa mọ wahala to ti waye kọja laarin ilu Mọdakẹkẹ ati Ifẹ le ṣi awọn agbofinro lọna lati le mu awọn ẹniibi ti wọn ṣiṣẹ naa.

Ọọni gboṣuba fun ijọba ipinlẹ Ọṣun, awọn agbofinro, ọtẹlẹmuyẹ, awọn ọmọ ologun, awọn figilante atawọn oṣiṣẹ alaabo mi-in fun bi wọn ṣe jigiri si ojuṣe wọn lasiko iṣẹlẹ naa, ti alaafia si jọba laarin ilu mejeeji.

Bakan naa lo rọ awọn araalu lati fọkanbalẹ, ki wọn mọ pe oju ọdaran nijọba yoo fi wo awọn to ṣiṣẹ ibi naa nigbakuugba ti ọwọ ba tẹ wọn.

Leave a Reply