Ọọni yoo gbe igbesẹ lori iwọde tawọn oṣiṣẹ-fẹyinti ṣe nitori Oyetọla

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọọni tilu Ileefẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, ti ṣeleri lati da si ọrọ iwọde tawọn oṣiṣẹ-fẹyinti ṣe lanaa, Ọjọbọ, Wẹsidee.

Pẹlu omije loju ati aṣọ dudu lọrun lawọn oṣiṣẹ-fẹyinti nipinlẹ Ọṣun fi wọ kaakiri ilu Ileefẹ ti wọn si pari irin wọn si aafin Ọọni Ogunwusi.

Akole: Gomina Oyetola, oku ko le jegbadun ise akanse oju ona

Oniruuru akọle ni wọn gbe lọwọ ti wọn si n kede pe odidi idaji owo ọgbọn oṣu nijọba ipinlẹ Ọṣun ko fun awọn.

Comrade Niyi Adefare to ṣaaju awọn oṣiṣẹ-fẹyinti ọhun ṣalaye laafin Ọọni pe iya nla lo n jẹ gbogbo awọn tiletile, bẹẹ lawọn si ti di alagbe laarin ilu.

O ni arugbo lo pọ ju ninu awọn, o si nira lati ri owo itọju san nileewosan latari airi owo gba lọwọ ijọba.

Laadin Ileefẹ, Oloye-agba Kayọde Awofiranye, to gba awọn eeyan naa lorukọ Ọọni, ba wọn kẹdun gbogbo nnkan ti wọn sọ pe awọn n la kọja.

Awofiranye sọ fun wọn pe oun yoo jiṣẹ wọn fun Ọọni, kabiyesi yoo si gbe igbesẹ lọgan lati ri ijọba ipinlẹ Ọṣun lori ọrọ wọn.

Awon oluwode

Leave a Reply