Faith Adebọla
Ireti awọn ọmọ Naijiria lati ṣẹgun arun buruku Koronafairọọsi ti tubọ fẹsẹ rinlẹ pẹlu bi abẹrẹ ajẹsara to n dena arun naa ti de bayii.
Nnkan bii wakati meloo kan sẹyin ni baalu Emirate Airlines kan ko awọn egboogi ti wọn porukọ ẹ ni Oxford-Astrazeneca naa wọle, papakọ ofurufu Nnamdi Azikiwe, l’Abuja, ni baluu naa balẹ si lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii.
Eyi ni igba akọkọ ti orilẹ-ede wa maa ri abẹrẹ ajẹsara Korona gba, wọn lontẹ ajọ ilera agbaye, World Health Organisation, wa lara awọn egbogi wọnyi, wọn fọwọ si i fun lilo.
Ijọba ti sọ ṣaaju latẹnu Minisita kekere feto ilera, Dokita Ọlọrunnibẹ Mamora, pe apa akọkọ lara awọn egboogi ọhun lo de yii, awọn maa wo bo ṣe ṣiṣẹ si, eyi lawọn fi maa pinnu lati beere fun pupọ si i, tabi kawọn beere fun oriṣii abẹrẹ ajẹsara mi-in.
Ko i ti i daju bi wọn ṣe maa ṣeto ati fun awọn araalu labẹrẹ naa, ati bo ṣe maa de awọn ipinlẹ kọọkan, ṣugbọn wọn ni iṣẹ ti n lọ lori eyi.