Awọn ajinigbe ti tu awọn mẹta ti wọn ji gbe niluu Oṣu silẹ

Florence Babaṣọla

Laipẹ yii ni iroyin naa jade pe awọn ajinigbe ti tu eeyan mẹta ti wọn ji gbe niluu Oṣu, loju ọna Ifẹ si Ileṣa lopin ọsẹ to kọja silẹ.

Seriki Hausa ti ilu Iyere, Haruna Tanko, ẹni ti aburo rẹ wa lara awọn ti wọn ji gbe naa fidi iroyin ọhun mulẹ fawọn oniroyin.

Iwadii fi han pe ajoṣepọ awọn ọlọdẹ pẹlu awọn ọlọpaa lo mu ko rọrun lati ri awọn eeyan naa gba kalẹ.

Bo tilẹ jẹ pe wọn ko ri eyikeyii mu lara awọn agbebọn naa, sibẹ, a gbọ pe wọn ko sanwo kankan lati gba wọn silẹ pẹlu bi awọn ajinigbe naa ṣe kọkọ n beere miliọnu lọna aadọta naira.

Leave a Reply