Ọpẹ o, awọn ajinigbe ti yọnda awọn dokita ti wọn ji gbe n’Idoani

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ 

Ọga awọn dokita ile-iwosan ijọba to wa n’Idoani, Dokita Olufẹmi Adeogun, atawọn oṣiṣẹ abẹ rẹ meji ti wọn ji gbe loju ọna Iwani, nijọba ibilẹ Ọsẹ, lalẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to kọja, lori ti ko yọ lọwọ awọn to ji wọn gbe bayii.

ALAROYE gbọ pe awọn mẹtẹẹta ni wọn bọ ninu igbekun awọn ajinigbe lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.

Lẹyin bii ọjọ mẹta ti wọn ti ji awọn oṣiṣẹ eleto ilera ọhun gbe lawọn ajinigbe ọhun too kan sawọn ẹbi wọn, ti wọn si ni afi dandan ki wọn san miliọnu mẹwaa Nairati wọn ba ṣi fẹẹ ri wọn pada laaye.

Wọn ni lẹyin ọpọlọpọ ẹbẹ lawọn ẹruuku ọhun ṣẹṣẹ gba lati din owo naa ku si miliọnu mẹfa pere.

Owo yii la gbọ pe wọn n tujọ lọwọ ti iroyin mi-in fi jade laaarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, pe wọn ti jajabọ lọwọ awọn oniṣẹẹbi naa lẹyin ọjọ marun-un ti wọn ti wa ni ikawọ wọn.

Ohun ti ọkan ninu awọn ẹbi dokita ọhun to b’ALAROYE sọrọ kọ lati fidi rẹ mulẹ ni boya wọn pada sanwo tawọn ajinigbe ọhun n beere fun ki wọn too da wọn silẹ tabi wọn ko san an.

Leave a Reply