Ọpẹ o, ijọba ti ṣi gbogbo ileewe pada nipinlẹ Eko

Faith Adebọla

Idunnu ti ṣubu lu ayọ fun gbogbo akẹkọọ atawọn obi nipinlẹ Eko bayii pẹlu bi ijọba ipinlẹ naa ṣe paṣẹ pe ki gbogbo awọn akẹkọọ pata lai yọ ẹkan kankan silẹ pada sẹnu ẹkọ wọn.

Ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹwaa, ọdun yii, iyẹn ọjọ Aje, Mọnde, to n bọ ni gbogbo ileewe pata, yala ti aladaani tabi ti ijọba yoo pada, ti awọn kilaasi kan tijọba ni ki wọn ṣi duro sile tẹlẹ naa yoo darapọ mọ awọn ẹlẹgbẹ wọn lati bẹrẹ si i gba ẹkọ pada nileewe kaluku wọn.

Ni nnkan bii oṣu mẹfa sẹyin ni ijọba paṣẹ pe ki gbogbo ileewe di titi pa ni kete ti ajakelẹ arun Koronafairọọsi gbode agbaye kan, ti kinni naa si n burẹkẹ nipinlẹ Eko, ati lawọn ipinlẹ mi-in nilẹ wa.

Ohun ti ijọba sọ ni pe, ileewe ti oun ni ki wọn ṣi pada yii, gbogbo ọmọ pata lo kan, paapaa awọn jẹle-o-sinmi (Daycare ati kindergarten)

Kọmiṣanna fun ọrọ ẹkọ l’Ekoo, Arabinrin Fọlaṣade Adefisayọ, sọ pe lẹyin ti ijọba ti wo ṣaakun eto imurasilẹ daadaa, ti asọyepọ to munadoko si ti waye laarin ijọba atawọn ti ọrọ kan, paapaa nidii ọrọ ẹkọ ati aabo lo fa a ti igbesẹ ọhun fi waye bayii.

O ti waa rọ gbogbo awọn ọga agba nileewe, paapaa lawọn ile ẹkọ aladaani lati pa gbogbo ofin ti ijọba ti la kalẹ mọ lori itankalẹ arun Koronafairọọsi, ki wọn si mu eto aabo wọn le dan-in-dan-in.

Adefisayọ fi kun un pe ijọba yoo tubọ maa mojuto eto igbaradi kaluku, ati pe ọfiisi naa ni yoo maa fun awọn to ba yege ni iwe-ẹri pe wọn ti yege.

Bijọba ti ṣe waa ni ki awọn ọmọleewe pada sẹnu ẹkọ wọn, bẹẹ lo rọ awọn adari ileewe, paapaa awọn ileewe aladaani lati ri i pe ki wọn gba iwe-ẹri ‘mo yege’ lati ṣi ileewe pada lọdọ ajọ eto ẹkọ, ki eto gbogbo le lọ gẹgẹ bii erongba ijọba.

 

Leave a Reply