Ọpẹ o, Korona ti lọ lara Igbakeji Gomina Kwara 

Stephen Ajagbe, Ilorin

Esi ayẹwo Igbakeji Gomina Kwara to tun jẹ alaga igbimọ to n gbogun ti arun koronafairọọsi, Kayọde Alabi, ti fi han pe ko ni arun naa lara mọ.

Alukoro igbimọ Covid-19 ni Kwara, Rafiu Ajakaye, lo sọ eleyii di mimọ ninu atẹjade kan to fi sita laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ yii. O ṣalaye pe ayẹwo ẹmeeji ọtọọtọ ti wọn ṣe fun un lọjọ Ẹti, Furaidee, fi han pe ara rẹ ti da ṣaka, o si maa pada sẹnu iṣẹ rẹ ni kiakia.

Ijọba dupẹ lọwọ gbogbo araalu fun aduroti ati adura wọn. Wọn tun gbadura fun ilera ati iwosan fun iyawo rẹ atawọn to ṣi n gba itọju nibudo iyasọtọ.

 

 

Leave a Reply