Jọkẹ Amọri
Titi di ba a ṣe n sọ yii ni ọkan-o-jọkan iṣẹ oriire n lọ sọdọ arẹwa oṣere tiata nni, Oluwaṣeyi Ẹdun, ati ọkọ rẹ, Johnson Adeniyi. Eyi ko sẹyin bi Ọlọrun ṣe ṣẹṣẹ ta idele naa lọrẹ ibeji lantilanti.
O pẹ ti ọmọbinrin yii ti n woju Ọlọrun fun ọmọ, gbogbo igba ni awọn ololufẹ rẹ si maa n gbadura fun un pe oun naa yoo finu ṣoyun, yoo si fi ẹyin gbe ọmọ pọn. Adura yii pada ṣẹ mọ oṣere naa lara, oun naa si ti di Iya Ibeji bayii.
O ṣe diẹ ti awọn kan ti n fura si oṣere naa ninu awọn fọto to fi maa n polowo ọja fawọn onibaara rẹ to maa n gbe jade. Niṣe ni awọn ti wọn ri fọto ibi ti oṣere naa ti sanra, to kun rọtọrọtọ daadaa yii n sọ nigba naa pe o jọ pe o ti di abara meji, ti wọn si n gbadura pe ki Ọlọrun jẹ ko jẹ ohun ti oju ati ọkan awọn n ṣọ fawọn nipa oṣere naa lo ṣẹlẹ o. Awọn ọmọran to maa n mọ oyun igbin ninu ikarahun sọ nigba naa pe o jọ pe Seyi ti loyun. Ni awọn ololufẹ rẹ ba bẹrẹ si i gbadura pe ki Ọlọrun jẹ ko ri bẹẹ.
Afi ni ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Keji yii, ti Adeniyi Johnson to jẹ ọkọ oṣere yii gbe e si ori ikanni Instagraamu rẹ pe ‘‘Halleluyah, emi ni baba ibeji tuntun nita bayii.
‘‘Emi ati iyawo mi duro fun odidi ọdun meje. Ṣibẹ, Ọlọrun jẹ Ọlọrun. Ọlọrun ṣeto rẹ lati jẹ ẹbun ọjọọbi fun mi. Ẹyin ọrẹ, mọlẹbi ati ololufẹ mi, inu mi dun, o si tẹ mi lọrun lati kede fun yin pe emi ni baba ibeji tuntun to wa nita bayii oo. Iyawo mi n ṣe daadaa, awọn ibeji naa si n ṣe daadaa. Mo dupẹ lọwọ gbogbo yin.
‘‘Ohun to fa a niyi ti mi o fi le ṣe ajọdun ọjọọbi mi, koda, mi o tiẹ ranti pe ọjọọbi mi ni mọ. Mo tọrọ aforiji lọwọ gbogbo ẹyin tẹ ẹ fi atẹjiṣẹ ranṣẹ si mi, ṣugbọn ti mi o le da a pada, mo mọ pe ihinrere yii yoo mu ki ẹ dariji mi.’’
Bi Adeniyi ṣe kọ ọ si ori ikanni rẹ niyi. Latigba naa ni gbogbo awọn ololufẹ rẹ, awọn afẹnifẹre ti n ki i ku oriire, ti wọn si n gbadura fun iya atawọn ọmọ tuntun naa.
Tẹ o ba gbagbe, Toyin Abraham ni ọkunrin toun naa jẹ oṣere yii kọkọ fẹ ko too di pe wọn kọ ara wọn silẹ, to si fẹ Ṣeyi Ẹdun.