Ọpẹ o, ọlọpaa ti mu were to pa ọmọ ọdun meje l’Ado-Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ajọ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ti kede pe ọwọ wọn ti tẹ obinrin were ẹni ọgbọn ọdun kan to pa ọmọ ọdun meje, Demilade Fadare, ni Ado-Ekiti, lọjọ Iṣẹgun, Tuside, ọsẹ to kọja yii.

Bakan naa ni awọn ọlọpaa tun kede pe ọwọ awọn ti tun tẹ oluṣọ aguntan ijọ Irapada (Redeemed) kan, Alagba Josiah Fadare ati iyawo rẹ, Eunice, to jẹ baba ati iya were naa.

Gẹgẹ bi Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, ṣe sọ, o ni were naa ni ọwọ awọn ọlọpaa tẹ niluu Ado-Ekiti, nibi to ti n rin kaakiri to si tun fẹẹ ṣe ẹsẹ miiran.

O ṣe alaye pe obinrin alaaganna naa ati awọn obi rẹ mejeeji ti wa ni atimọle awọn ọlọpaa, ti wọn si n sọ ohun ti wọn mọ nipa iṣẹlẹ naa.

Ti ẹ ko ba gbagbe, ọjọ Iṣẹgun, Tuside, ọsẹ to kọja yii, ni awọn ọdọ kan ni adugbo Adehun, ni Ado-Ekiti, fi ina si ile oluṣọ aguntan yii ni kete ti wọn ba oku ọmọ ọdun meje ti orukọ rẹ njẹ Demilade Fadare ninu ile rẹ to wa ni adugbo naa.

Ọmọde yii ti wọn ti n nwa lati alẹ ọjọ Mọnde ni wọn sọ pe iya rẹ ran niṣẹ lati lọọ ra ogi wa ni deede aago mẹjọ aabọ alẹ ọjọ naa, ti wọn ko si ri i titi di aarọ ọjọ keji, ki wọn too lọọ ba oku rẹ ninu ile oluṣọ aguntan naa.

Ọmọ ọdun meje yii to jẹ ọmọ ileewe alakọọbẹrẹ kan ni agbegbe Adehun, ni wọn sọ pe obinrin alaaganna yii to tun jẹ ọmọ bíbí oluṣọ aguntan naa, le, to si ba a ko too fi ada ṣa a wẹlẹwẹlẹ, to si ko o sinu abọ nla kan ninu ile naa.

Ṣaaju ni awọn obi Demilade ti kọkọ lọ ọ fi ọrọ naa lọ ni teṣan awọn ọlọpaa ni alẹ ọjọ naa.  Igbesẹ yii lo fa a ti awọn eeyan adugbo naa fi bẹrẹ wiwa Demilade, ki wọn too lọọ ba oku rẹ ninu ile naa ni kutukutu aarọ ọjọ Tuside.

Awọn eeyan adugbo naa ti wọn ba ALAROYE sọrọ ti wọn ko fẹ ki wọn darukọ wọn, ṣalaye pe obinrin alaaganna yii ti kọkọ ṣa baba rẹ ladaa ni nnkan bii oṣun meji sẹyin. Eyi lo fa a to fi lo ọsẹ meji nileewosan ko too pada wa si ile.

 

Leave a Reply