Ọpẹ o! Toyin Araham ti tun loyun, oun ati ọkọ rẹ n reti ọmọ keji

Jọkẹ Amọri
Inu idunnu nla ni oṣere ilẹ wa to gbajumọ daadaa nni, Toyin Abraham ti gbogbo eeyan mọ si Iya Ire, atawọn ololufẹ rẹ wa bayii. Eyi ko sẹyin ọlẹ ayọ to tun sọ ninu oṣere naa lẹyin ọmọkunrin ti Ọlọrun ti fi ta a lọrẹ ṣaaju ti wọn pe ni Ireoluwa.
Lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ni oṣere naa gbe fidio kan ti oun ati ọkọ rẹ jọ wa sori ikanni Instagraamu rẹ, to si kọ ọ sibẹ pe, ‘‘A ku oṣu tuntun, oṣu Karun-un wa yoo kun fun ọpọlọpọ iyanu.’’
Yatọ si kiki yii, awọn to wo fidio naa ṣakiyesi pe ikun oṣere naa yọ sita ninu aṣọ to wọ, eyi to ṣafihan pe o ti loyun.
Bi awọn ololufẹ rẹ ṣe ri ikun Toyin to ta jade ninu aṣọ to wọ, ti yiyọ naa si kọja ti ẹni to ṣẹṣẹ jẹ amala ati eweedu tan ni wọn bẹrẹ si i ki i ku oriire, ti wọn si n gbadura kikan kikan fun un pe ẹsẹ rẹ yoo telẹ layọ.
Lara ọrọ ikinni ti awọn ololufẹ rẹ kọ sibẹ ni pe ‘ọmọ mi-in tun n bọ lọna, abi oju mi ko ri i daadaa ni.’
Ẹlomi-in tun kọ ọ si abẹ fidio naa pe ‘Ọlọrun, jọwọ, jẹ ki ọmo yii jẹ obinrin.’’ Bẹẹ ni ẹnikan tun kọ ọ pe arabinrin mi ti tobi fun oyun o.’’ Oriṣiiriṣii awọn ọrọ iwuri ati adura lawọn ololufẹ Toyin n rọ le e lori pe ẹsẹ rẹ yoo tẹlẹ layọ.
Tẹ o ba gbagbe, oṣere naa ko rọmọ bi ni gbogbo asiko to fi fẹ ọkọ rẹ akọkọ, iyẹn Adeniyi Johnson. Nigba to kọ ọkunrin naa silẹ to tun pada fẹ oṣere ẹgbẹ rẹ mi-in ti wọn n pe ni Kọlawọle Ajeyẹmi ni Ọlọrun ṣina fun un, to si bi ọmọkunrin kan ninu oṣu Kẹjọ, ọdun 2019, ti wọn sọ ni Ireoluwa.
Bo tilẹ jẹ pe ọmọ yii ni akọbi ti Toyin yoo bi fun Kọlawọle, ọkọ rẹ ti ni omọbinrin kan to dagba, iyẹn Temitọpẹ Ajewọle ti Toyin ti gba sọdọ, to si mu un bii ọmọ to bi ninu ara rẹ.
O ti to ọjọ mẹta ti wọn ti n gbe e pooyi ẹnu pe ọṣerebinrin yii ti loyun, paapaa awọn ti wọn ri i lasiko ti Fẹmi Adebayọ ṣafihan fiimu rẹ to pe ni ‘King of Thieves’. Aṣọ gbagẹrẹ kan ni oṣere yii wọ, yatọ si pe o ti tobi si i, o han loju rẹ pe o rẹ ẹ, oju rẹ ko si ṣe daadaa nibi eto naa. Latigba naa lawọn eeyan ti n sọ pe o jọ pe Toyin ti loyun, o si yẹ ko lọọ fun ara ni isinmi.
Adura ni gbogbo awọn ololufẹ oṣere naa n gba fun un pe ẹsẹ rẹ yoo tẹlẹ layọ.

Leave a Reply