Ọpẹ o, wọn ti tu pasitọ Deeper Life ti wọn ji gbe l’Akurẹ silẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Pasitọ ijọ Deeper Life ti wọn ji gbe ninu sọọsi rẹ, Ọtamayọmi Ogedemgbe, ti gba itusilẹ lẹyin bii ọsẹ kan gbako to ti wa ninu igbekun awọn to ji i gbe.

Nnkan bii aago mẹsan-an alẹ ku bii isẹju diẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to kọja, lawọn ajinigbe ọhun lọọ ka Ogedemgbe mọ inu sọọsi ibi to ti n ṣe isin fawọn ọmọ ijọ rẹ lọwọ, tí wọn sì fipa wọ ọ ju sinu ọkọ Toyota Corolla alawọ dudu kan ti wọn gbe wa, eyi ti wọn fi wa olusọaguntan naa lọ sibi tẹnikẹni ko mọ.

Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja, lawọn ajinigbe ọhun kan sawọn ẹbi rẹ, tí wọn sì ni miliọnu lọna ọgbọn naira lawọn yoo gba lọwọ wọn ki awọn too tu ẹni ami ororo naa silẹ.

A ko ti i le sọ ní pato boya awọn ẹbi olusọaguntan ọhun sanwo fawọn janduku naa tabi wọn ko san lasiko ta a fi n kọ iroyin yii lọwọ.

Leave a Reply