Ọpẹ o, wọn ti ri awọn agbẹ mẹrin ti wọn ji gbe ni Ikosun-Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Awọn ọlọpaa nipinlẹ Ekiti ni Satide, ọjọ Abamẹta, ti kede pe awọn ti ṣe awari awọn agbẹ mẹrin ti awọn ajinigbe ji gbe ninu oko wọn niluu Ikosun-Ekiti, ijọba ibilẹ Mọna, nipinlẹ Ekiti.

Bi ẹ ko ba gbagbe, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ to kọja yii, ni awọn ajinigbe yii ti wọn dihamọra ṣadeede wọ inu oko awọn agbẹ wọnyi, ti wọn si ji wọn gbe lọ.

Lẹyin ọjọ keji ti wọn ji awọn agbẹ wọnyi gbe ni wọn beere aadọta miliọnu lọwọ awọn mọlẹbi wọn, awọn agbẹ wọnyi, ti meji lara wọn jẹ dẹrẹba to n wa ọkọ katakata ti wọn fi n kọ ebe ti wọn n pe ni Agiriiki.

Ọkan lara awọn mọlẹbi awọn agbẹ wọnyi to ba ALAROYE sọrọ ti ko fẹ ka darukọ oun ṣalaye pe mọlẹbi awọn agbẹ naa san miliọnu meji aabọ

naira, ki wọn too tu wọn silẹ.

O fi kun un pe ọkan lara awọn agbẹ naa ti eto ilera rẹ ko dan mọran lo jẹ ki wọn tete tu awọn agbẹ naa silẹ ati lati jẹ ki wọn gba iye owo to wa lọwọ wọn lẹyin idunaa-dura to waye laarin ọjọ marun-un gbako ti wọn ti ko awọn agbẹ wọnyi.

O ṣalaye pe nirọlẹ ọjọ Satide ni awọn agbẹ naa ṣadeede fi ẹsẹ wọn rin waa ba awọn mọlẹbi wọn niluu Ikosun, nibi ti wọn ti n ṣe ipade lori bi wọn yoo ṣe ri owo ti wọn ti fun awon ajinigbe naa.

Nigba ti ALAROYE beere bi wọn ṣe ri owo naa, ọkunrin yii sọ pe gbogbo awọn araalu ati awọn agbẹ lo da owo ti wọn lọọ fun awọn ajinigbe naa.

Ṣugbọn ninu iwe kan ti Alukoro ọlọpaa ipinle Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, fi ṣọwọ si awọn oniroyin niluu Ado-Ekiti, o sọ pe gbogbo awọn agbẹ naa lo gba iyọnda lẹẹkan naa, ti wọn si ti darapọ mọ awọn mọlẹbi wọn.

Abutu ṣalaye pe awọn ọlọpaa ati awọn Amọtẹkun pẹlu awọn ọdẹ ibilẹ to wa ni agbegbe naa ko ni isinmi latọjọ ti wọn ti ko awọn agbẹ wọnyi lọ.

Alukoro ọlọpaa yii ni awọn agbofinro ti tun bẹrẹ igbesẹ to nipọn lagbegbe naa lati foju awọn ajinigbe to n da agbegbe naa laamu han, ati pe awọn ọlọpaa ṣe eleyii lati fopin si iṣẹlẹ ajinigbe to n waye lemọlemọ ni agbegbe naa lati nnkan bii oṣu meji sẹyin.

Leave a Reply