Ọpẹ o, wọn ti ri awọn arinrinajo tawọn ajinigbe ji gbe loju-ọna Oṣogbo si Ibokun

Florence Babaṣọla

 

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti kede pe eeyan meje tawọn ajinigbe ji lalẹ ọjọ keji, oṣu kẹta, ọdun yii, loju-ọna Oṣogbo si Ibokun, ti gba ominira bayii.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, SP Yẹmisi Ọpalọla, fi sita lo ti ṣalaye pe igbiyanju Kọmiṣanna ọlọpaa, Ọlawale Ọlọkọde, ati ifọwọsowọpọ awọn ikọ alaabo to ku lo jẹ ki aṣeyọri naa ṣee ṣe.

O ni lati ọjọ iṣẹlẹ ọhun lawọn ikọ alaabo gbogbo ti wa ninu igbo lagbegbe naa, nigba ti ifinnamọni yii si pọ, lawọn ajinigbe ọhun tu awọn mejeeje silẹ.

O ni laipẹ ni wọn yoo fa awọn eeyan ọhun le awọn mọlẹbi wọn lọwọ.

Ileeṣẹ ọlọpaa waa ke si awọn araalu lati ma ṣe fi ohunkohun pamọ fawọn agbofinro nipa aabo, bẹẹ lo si fi da wọn loju pe awọn ọlọpaa ko ni i sinmi titi ti ohun gbogbo yoo fi wa bo ṣe yẹ ko ri.

 

Leave a Reply