Opẹ o, wọn ti tu Sunday Igboho silẹ lahaamọ

Ijọba orileede Olominira Benin ti tu gbajugbaja ajijangbara ilẹ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ, ti gbogbo eeyan mọ si Sunday Igboho, silẹ, lahaamọ ti wọn fi i si.

Owurọ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ keje, oṣu Kẹta yii, lawọn agbofinro tu u silẹ, ti wọn si fa a le Ọjọgbọn Banji Akintoye, olori ẹgbẹ Ilana Ọmọ Odua, lọwọ, ko le lọọ boju to ara rẹ.

Nnkan bii ojilerugba din mẹsan-an (231) ọjọ, lọkunrin naa fi wa lahaamọ, niluu Kutọnu, nigba ti wọn mu un ninu oṣu Keje, ọdun to kọja, lasiko toun ati iyawo rẹ fẹẹ wọ baaluu lọọ sorileede Germany.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kin-ni-ni, osu Keje, ọdun to kọja, lawọn ẹṣọ ọtẹlẹmuyẹ DSS lọ ṣakọlu sile ọkunrin naa ni ipinlẹ Ọyọ, ti wọn si ba dukia rẹ jẹ.

Sunday Igboho jẹ ọkan ninu awọn olewaju to n pe fun idaduro ati ominira ilẹ Yoruba, kuro lara Naijiria.

 


Leave a Reply