Ọpẹlọpẹ awọn ṣọja, ọọdunrun ọmọleewe lawọn agbebọn tun fẹẹ ko lọ ni Kaduna

Faith Adebọla

Ko jọ pe wahala awọn janduku agbebọn to n ji awọn ọmọleewe gbe lagbegbe Oke-Ọya yoo rọlẹ bọrọ tori kaka kewe agbọn dẹ, niṣe lo n le koko si i lọrọ naa da. Awọn agbebọn yii tun ti lọọ ji awọn ọọdunrun o le meje ọmọleewe (307) gbe laaarọ ọjọ Aiku, Sannde yii, ọpẹlọpẹ awọn ṣọja ni o jẹ ki wọn ko wọn wọ’gbo, wọn ri awọn ọmọ naa gba pada.

Ileewe ijọba Government Science Secondary School, to wa ni lagbegbe Ikara, nipinlẹ Kaduna, niṣẹlẹ naa ti waye, ibẹ lawọn agbebọn ya bo ni nnkan bii aago marun-un idaji ọjọ Aiku yii, wọn si ti ko awọn akẹkọọ ogo-wẹẹrẹ naa, ṣugbọn wọn lawọn kan lara awọn akẹkọọ naa ti dọgbọn tẹ aago idagiri tijọba ti ṣe sileewe wọn, gbara ti wọn ti ri ohun to n ṣẹlẹ. Aago yii tawọn agbofinro gbọ ni wọn lo jẹ kawọn ọlọpaa atawọn ṣọja sare dihamọra lọ sibi iṣẹlẹ naa, ti wọn si ṣe kongẹ bi awọn ọdaju ẹda yii ṣe fẹẹ ko awọn ọmọ naa lọ, ni wọn ba fija pẹẹta pẹlu wọn.

Kọmiṣanna fun eto aabo abẹle ati ọrọ ile nipinlẹ Kaduna, Ọgbẹni Samuel Aruwan, lo sọrọ yii di mimọ lọjọ Aiku, o ni: “A dupẹ pe wọn ṣaṣeyọri o, ọpẹlọpẹ awọn ṣọja ileeṣẹ ologun ilẹ wa ti wọn tete gbe igbesẹ akin gbara ti olobo ti ta wọn lori iṣẹlẹ naa. Aijẹ bẹẹ, ọọdunrun o le meje (307) lawọn ọmọ wa tawọn agbebọn naa ti ji gbe, wọn tun fẹẹ ko wọn wọgbo lọ.

“Awọn agbebọn naa ti sa lọ, nigba ti wọn ri awọn agbofinro. Ṣugbọn awọn ọlọpaa atawọn ṣọja ṣi n tọpasẹ wọn lọ lati mu wọn,” gẹgẹ bi Samuel ṣe sọ.

Tẹ o ba gbagbe, awọn akẹkọọ bii mẹtadinlogoji ti wọn lawọn agbebọn naa ji gbe wọ’gbo lọ lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii, ṣi wa lakata wọn, wọn o ti i tu wọn silẹ. Ileewe Federal College of Forestry Mechanisation ni wọn ti ji wọn ko.

Iya gidi ni wọn si fi n jẹ awọn akẹkọọ yii ninu igbo ti wọn gbe wọn lọ ninu fidio kan to jade nipa wọn. Bẹẹ lawọn ọmọ yii n bẹbẹ pe ki ijọba jọwọ, waa tu awọn silẹ ni igbekun awọn ajinigbe yii. Bọlọ ni awọn to jẹ obinrin ninu awọn akẹkọọ yii n sunkun, aṣọ nikan ni wọn si ro mọya ninu fidio to ṣafihan wọn naa, ọpọ ninu wọn ko wẹwu rara.

Wọn lawọn agbebọn naa ni miliọnu lọna ẹẹdẹgbẹta (500m) lawọn maa gba ki wọn too da awọn akẹkọọ naa nide lakata wọn.

Leave a Reply