Ọpẹyẹmi, ọmọ Alabi Pasuma, gbaṣẹ ologun l’Amẹrika, ṣinkin ninu Paso n dun

Jide Alabi

Ninu idunnu nla ni gbajumọ olorin fuji nni, Alaaji Wasiu Alabi Pasuma, wa bayii lori bi ọkan lara awọn ọmọ ẹ, Ọpẹyẹmi, ṣe di ọmọ ogun oju omi lorilẹ-ede Amerika.

Lori ikanni Instagram Wasiu Alabi Pasuma ni ọkunrin olorin fuji yii gbe iroyin oriire ọhun si, nibi to ti sọ pe ọmọ oun naa ti di ọkan lara awọn ologun niluu oyinbo.

O ni, “Mo ki ara mi ku oriire lori bi ọmọ mi ṣe di ọmọ ogun oju omi l’Amerika. Ọmọ mi daadaa, Ọpẹyẹmi l’Amẹrika, ku oriire o, ni gbogbo igba lo maa n mu inu emi ati iya ẹ dun daadaa, mo bẹ Ọlọrun ko ba mi bukun ẹ ninu ọna ti o yan yii.”

Ninu awọn olorin fuji ti wọn n ṣe daadaa ni Naijiria loni-in ni Alabi Pasuma wa, bẹẹ lo ni awọn ọmọ ti wọn n ṣe daadaa pẹlu. Bo ti ṣe ni agbabọọlu ninu awọn ọmọ ẹ, bẹẹ lo tun ti ni ologun bayii, ti awọn mi-in paapaa si tun kawe jade yunifasiti.

Leave a Reply