Faith Adebọla, Eko
Ijamba iku ojiji tun ja bii iji niluu Eko l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejila, oṣu Kẹrin, ta a wa yii, pẹlu bi ile alaja meje kan ti wọn n kọ lọwọ ṣe rọ da lulẹ wii lojiji, a gbọ pe ọpọ eeyan lo fara pa yanna-yanna nibi iṣẹlẹ ọhun, ti ọpọ, paapaa awọn oṣiṣẹ ṣi ha sabẹ ẹbiti ọhun, bo tilẹ jẹ pe titi dasiko ta a fi n ko iroyin yii jọ, ko ti i si aridaju boya ẹmi eeyan sọnu sabẹ awoku naa, tori wọn o ti i ri oku kankan hu jade.
Iṣẹlẹ yii waye ni nnkan bii aago mẹta ọsan kọja iṣẹju diẹ, nibi tiṣẹ ikọle alaja gogoro kan ti n lọ lọwọ lagbegbe Banana Island, n’Ikoyi, l’Erekuṣu Eko.
Banana Island yii wa lara awọn ibi ti nnkan ti wọn ju lọ lorileede yii, latari bo ṣe jẹ iṣẹ-ọna ati imọ ẹrọ igbalode ni wọn fi ṣẹda Erekuṣu ta a n sọrọ rẹ yii.
Gẹgẹ bii alaye ṣoki kan ti Agbẹnusọ fun ileeṣẹ panapana ipinlẹ Eko, Ọgbẹni Amodu Shakiru, ṣe lori iṣẹlẹ naa, o ni ijamba yii waye gẹrẹ tawọn oṣiṣẹ to n ṣiṣẹ nibi ikọle naa ti ṣiwọ iṣẹ ọjọ naa, amọ ọpọ ninu wọn ni wọn ṣi n paarọ aṣọ, ti wọn si n tunra ṣe lọwọ, lasiko ti ile naa ya lulẹ.
O lawọn ẹṣọ alaabo atawọn ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko, LASEMA, ati tijọba apapọ, NEMA, titi kan ileeṣẹ panapana, ti sare de ibi iṣẹlẹ ibanujẹ yii, iṣẹ si ti n lọ lọwọ lati doola ẹmi awọn ti wọn ha saarin awoku naa.
“Aago mẹrin ku iṣẹju meji irọlẹ la gba ipe idagiri nileeṣẹ wa, pe ile alaja meje kan ti tun ya lulẹ ni Banana Island, l’Ekoo. A o ti i le sọ boya awọn eeyan ha sabẹ awoku naa, amọ a gbe awọn to fara gbọgbẹ ta a kọkọ ri layiika awoku naa lọ sọsibitu fun itọju pajawiri,” gẹgẹ bo ṣe wi.
Alaroye yoo maa fi iroyin iṣẹlẹ naa to ẹyin olugbọ wa leti bo ṣe n lọ si.
CAPTION