Ọpọ eeyan ku, awọn mi-in fara pa, nibi ijamba ọkọ to waye l’Akungba Akoko

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ 

Ọpọlọpọ eeyan ni wọn ku, tawọn mi-in si tun fara pa ninu ijamba ọkọ kan to waye niluu Akungba Akoko lalẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ ta a wa yii.

ALAROYE fidi rẹ mulẹ lati ẹnu ẹnikan tiṣẹlẹ yii ṣoju rẹ, Ọgbẹni Ọṣọ, pe ọkọ ajagbe kan lo padanu ijanu rẹ lasiko to n sọkalẹ Okerigbo, lagbegbe Fasiti Adekunle Ajasin, to wa loju ọna marosẹ Akungba si Ikarẹ Akoko ni nnkan bii aago mẹsan-an aabọ alẹ ọjọ naa.

Ọṣọ ni ọpọlọpọ awọn ọkọ akero ati ọlọkada to n lọ jẹẹjẹ wọn lasiko naa lọkọ ajagbe yii fori sọ, leyii to ṣokunfa ọpọ eeyan to ba iṣẹlẹ yii rin, ti ọpọ si tun farapa yannayanna.

Ọkunrin yii ni ko ti i ṣeni to ti i le sọ ni pato iye awọn eeyan to ku atawọn to farapa nigba to fi n ba wa sọrọ latari asiko ti ijamba naa waye.

O ni oun foju ara oun ri oku eeyan bii mẹjọ ti wọn fa jade, nigba ti wọn ko ti i mọ iye awọn to si wa labẹ awọn ọkọ ati awọn to ko sinu odo nla kan to wa lagbegbe naa.

One thought on “Ọpọ eeyan ku, awọn mi-in fara pa, nibi ijamba ọkọ to waye l’Akungba Akoko

  1. Afi ki Olorun Oba ko maa so wa kama rarin fese si ninu irin ajo wa
    Awon to ba ijanba oko na lo ki Oluwa tewon safefe rere, awon to farapa naa ki Oluwa mu won lara da. A o ni sirin o ni agbara Olorun Oba Amin

Leave a Reply