Opurọ buruku lawọn ṣọja Naijiria, Fẹmi Falana lo sọ bẹẹ 

Aderounmu Kazeem

Gbajumọ ajafẹtọọ nni,  Fẹmi Falana, ti sọ pe, ibẹrubojo ni ko ni i jẹ ki pupọ ninu awọn eeyan ti wọn padanu ọmo wọn ninu ikọlu to waye ni Lẹkki le yọju sita. Ati pe awọn ṣọja ilẹ yii ko sọ ootọ ẹyọ kan bayii lori iṣẹlẹ naa, irọ nla ni wọn n pa fọmọ Naijiria gbogbo.

Ninu ifọrọwerọ kan ti Amofin agba yii ṣe pẹlu oludasilẹ ileeṣẹ iwe iroyin Sahara, Ọmoyẹle Ṣoworẹ, lori ẹrọ alatagba Zoom ni Falana, ti sọrọ yii.

O ni ọrọ orilẹ-ede yii ye awọn eeyan ẹ yekeyeke, nitori ẹ gan-an lọpọ ninu awọn ti wọn gbe digbadigba lọ si ọsibitu lasiko ti ibọn ba wọn ni Lẹkki fi yara gba ile wọn lọ ni kete ti wọn ti gbadun diẹ.

Falana fi kun un pe ohun ti wọn sọ fawọn eeyan ọhun ni pe awọn gan-an ni ijọba yoo da ọrọ ọhun le lori nigba to ba ya, ti wọn yoo si ba wọn ṣẹjọ gidi. O lohun tawọn mi-in gbọ ninu wọn niyẹn, ti wọn fi yara ba ẹsẹ wọn sọrọ  ni kete ti alaafia ti to wọn lara.

Ninu ọrọ ẹ naa lo ti rọ ajọ orilẹ-ede agbaye ki wọn ma ṣe da ileeṣẹ oloogun lohun lori awijare wọn nipa ikọlu to waye ni too-geeti Lẹkki, l’Ekoo.

Falana, sọ pe opurọ aye lawọn ṣọja Naijiria, ati pe wọn ko ṣẹṣẹ maa parọ. O ni ti eeyan ba ti n wa gbogbo ibajẹ aye pata, lọdọ awọn ologun Naijiria gan-an ni ki wọn wa a si.  O lawọn oloogun lo ti kọkọ sọ pe awọn kọ lawọn kọlu awọn ọdọ to n ṣewọde, nigba to tun ya ni wọn sọ pe awọn lawọn wa nibẹ, ati pe ijọba Eko lo ni ki awọn lọ sibẹ.

Falana, ti waa rọ awọn orilẹ-ede agbaye ki wọn ma ṣe gba ọrọ awọn ileeṣẹ ologun Naijiria gbọ rara, nitori bi wọn ti ṣe mọ irọ pa daadaa, bẹẹ ni iwa eru mi-in bii ikowojẹ ati ẹtan kun ọwọ wọn.

Amofin agba yii waa fi kun un pe niwọn igba ti Gomina Babajide Sanwo-Olu ti gba wi pe loootọ leeyan meji ku lasiko ikọlu ọhun, dajudaju awọn meji to ku yii, awọn ṣọja ti wọn ran niṣe naa lo pa wọn atawọn mi-in ti oku wọn ti dawati bayii, ti ibẹrubojo ko jẹ ki awọn eeyan wọn jade lati sọrọ. O ni ọrọ ṣi n bọ lori ẹ lai pẹ rara, aṣiri gbogbo yoo si tu sita.

 

Leave a Reply