Ọran ma waa de bayii o! Pasitọ fun ọmọ ẹ loyun lẹẹmẹta l’Owode-Ẹgbado, o tun ṣẹ ẹ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Pasitọ Ṣọọṣi CAC, Ogo Oluwa Parish, nipinlẹ Ogun, ni baba tẹ ẹ n wo fọto rẹ yii. Oluwafẹmi Oyebọla lorukọ rẹ, ẹni ọdun mẹrinlelogojii(44) ni. Oun lo bẹrẹ si i ba ọmọ rẹ obinrin laṣepọ lati ọdun 2015, to si fun ọmọ naa loyun lẹẹmẹta ọtọọtọ, bẹẹ lo ba a ṣẹyun ọhun kaṣiiri ma baa tu.

Iyawo Oyebọla lo ṣalaisi lọdun 2015, afi bii pe iyawo ẹnikan ko ku ri, n ni pasitọ yii ba n wa ẹni ti yoo maa ba sun lẹyin iku iyawo ẹ to bimọ obinrin yii fun un.

Eyi ti ko ba si fi fẹyawo mi-in, ọmọ rẹ obinrin to wa lẹni ọdun mọkandinlogun nigba naa lo bẹrẹ si i ba a sun, o si ṣe kinni naa fọdun marun-un gbako.

Lawọn asiko to n ba ọmọbinrin naa sun niyẹn loyun lẹẹmẹta, Oyebọla si mu ọmọ rẹ lọ sibi ti wọn yoo ti ṣẹyun ọhun bo ṣe n duro, wọn si ṣẹ wọn danu.

Ko ma baa di pe ọmọ rẹ yoo tun loyun mi-in, niṣe ni pasitọ yii ṣeto ifetosọmọbibi fọmọ rẹ, o fẹẹ maa ba a lo pọ lai si ibẹru oyun nini, nigba naa lo si tẹra mọ iṣẹkuṣe naa gidi.

Ọmọ rẹ to ti pe ọdun mẹrinlelogun bayii lo ṣẹṣẹ waa ronu wo pe baba oun fẹẹ sọ ere buruku naa di nnkan gbere ni, ko daju pe oun yoo bọ lọwọ rẹ laye yii pẹlu famili pilaani to tun ṣe soun lara naa. N lọmọ ba fi ọrọ ara ẹ lọ awọn ajafẹtọọ ọmọniyan ti wọn n pe ni ‘Advocacy For Children And Vulnerable Persons Network’.

Awọn iyẹn lo ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ọlọpaa teṣan Owode-Ẹgbado, nibi ti SP Ọlabsi Elebute ti jẹ DPO wọn.

Wọn wa Pasitọ Oluwafẹmi Oyebọla dele rẹ, wọn mu un de teṣan ọlọpaa, o si jẹwọ pe ootọ pọnbele ni gbogbo ohun tọmọ oun sọ fun wọn naa.

O ni boun ṣe jẹ baba ẹ naa loun tun n ba a sun latọdun karun-un, oun si ti ṣẹyun mẹta fun un loootọ, ifetosọmọbibi to si sọ pe oun ṣe naa ki i ṣe irọ rara.

CP Kenneth Ebrimson, ọga ọlọpaa nipinlẹ Ogun, ko fi ọrọ rẹ falẹ to fi ni ki wọn gbe pasitọ naa lọ sẹka to n ri si ifiyajẹ ọmọde ati lilo wọn nilokulo. Ibẹ ni wọn yoo ti gbe pasitọ ti ko le ko ara ẹ nijanu ibasun naa lọ sile-ẹjọ.

One thought on “Ọran ma waa de bayii o! Pasitọ fun ọmọ ẹ loyun lẹẹmẹta l’Owode-Ẹgbado, o tun ṣẹ ẹ

  1. Olorun nikan lo le gba wa ni iru akoko bi eyi. Opin aye ti de, iwe mimi Bibeli fi ye wa pe ki a ma sora, ki a si ma gbadura ki a ma ba a bo sinu idewo igba ikehin. Ko si eniti esu ko le lo, idi niyi ti Bibeli se so wipe; enti o ba ro pe oun duro, ki o ma ye ara re wo, ki o ma ba subu.

Leave a Reply