Ọrẹ meji to pa awọn ọmọde l’Ado-Ekiti ti wa lẹwọn

Jide Alabi

Ileeṣẹ ọlọpaa ti ko awọn ọkunrin meji kan, Ayẹni Abọlarin, ati Ajayi Oluwaṣeun, lo sile-ẹjọ lori ẹsun pe wọn pa awọn ọmọ keekeeke meji kan nipinlẹ Ekiti.

Ẹni ọdun mejilelogoji ni Ayẹni, nigba ti Ajayi jẹ ẹni ọdun mejilelọgbọn. Ọkunrin kan ati obinrin kan lawọn ọmọ keekeeke meji ti wọn pa yii, ọkunrin jẹ ọmọ ọdun marun-un, nigba ti obinrin jẹ ọmọ ọdun meje.

Iṣẹ ni baba-baba wọn ran awọn ọmọ yii, nigba yi wọn yoo si fi ri wọn, ninu mọto akọku kan ni wọn ti ba oku wọn, lẹyin ti wọn ti wa wọn kiri titi.

Ọjọ kọkanla, oṣu kẹwaa, ọdun yii, ni wọn sọ pe iṣẹlẹ ọhun waye niluu Ado-Ekiti, nipinlẹ Ekiti.

Ẹsun onikoko meji ni wọn ka si awọn ọkunrin mejeeji yii lẹsẹ, ẹsun pe wọn gbero lati paayan, ati ipaniyan ni wọn fi kan wọn.

Ọlọpaa to wa lori ọrọ ọhun, Ọgbẹni Caleb Leranmo, sọ ni kootu lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, pe niṣe lawọn mejeeji ọhun mọ ọn mọ ṣeku pa awọn ọkọ keekeke ọhun ni.

Ni bayii, Adajọ Abdulhamid Lawal ti sọ pe ki wọn lọọ fi wọn pamọ sọgba ẹwọn na, nigba ti ẹjọ ọhun yoo maa tẹ siwaju lọjọ kẹtalelogun, oṣu kejila, ọdun yii.

 

Leave a Reply