Ọrẹ meji yan’ra wọn lale, lo ba doyun, ni wọn ba sin ọmọ to fi bi laaye

Monisọla Saka

Pako bii maaluu to rọbẹ ni awọn ọrẹ meji kan ti wọn yan’ra wọn lale titi ti wọn fi funra wọn loyun, ti wọn si lọọ sin ọmọ ti wọn bi latari òwò-ale naa laaye, n wo bayii lakolo ọlọpaa Dutse, nipinlẹ Jigawa.

Ọwọ awọn agbofinro tẹ awọn ọdaju ẹda meji yii, Balaraba Shehu ati ọrẹkunrin ẹ, Amadu Sale, lori ẹsun pe wọn yan ara wọn lalẹ, tibitibi ti wọn ṣe si doyun, niyaale ile naa ba foyun ọhun bimọ. Nitori itiju to le tidi ọrọ naa yọ lawọn mejeeji fi gbimọ pọ, wọn si bo ọmọ tuntun naa mọlẹ laaye. Ṣugbọn aṣiri wọn pada tu, awọn agbofinro si mu wọn.

DSP Lawan Shiisu, ti i ṣe Alukoro ọlọpaa ipinlẹ naa to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ sọ pe lẹyin ti Balaraba ri i pe ọmọ ale loun bi, nitori òwò-àlè lo ṣokunfa ọmọ to waye naa, nitori ki i ṣe pe igbeyawo kan so oun ati ọkunrin naa pọ, lo lọọ lẹdi apo pọ mọ Amadu to fun un loyun lati ṣiṣẹ ibi ọhun. Ilẹ sukẹsukẹ kan ni obinrin naa gbẹ nitosi ile igbọnsẹ inu ile ti wọn n gbe, ibẹ lo si sin ọmọ naa si lai jẹpe o ti ku.

O ni, “Ni nnkan bii aago mejila oru ku iṣẹju mẹwaa, lọjọ keji, oṣu Kejila, ọdun yii, lawọn eeyan kan pe teṣan awọn pe awọn fura si obinrin ẹni ọgbọn ọdun kan, Balaraba Shehu, to n gbe l’Abule Tsurma, nijọba ibilẹ Kiyawa, nipinlẹ Jigawa, pe o ti bi oyun inu ẹ, o si ti lọọ sin ọmọ naa lai ti i ku rẹ.

‘‘Ni kete ti a gbọ iroyin ọhun lawọn ikọ agbofinro kan kọja sibi ti iṣẹlẹ naa ti waye. Loju-ẹsẹ lawọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ti bẹrẹ iṣẹ, ẹgbẹ ileewẹ inu ile ọhun to sin in si naa ni wọn ti hu ọmọ yẹn jade. Bo tilẹ jẹ pe wọn du ẹmi ọmọ naa pe boya Ọlọrun le jẹ ki o ye, ṣugbọn o ṣe ni laaanu pe bi wọn ṣe n gbe e de ọsibitu nla ijọba to wa ni Dutse, ni dokita sọ fun wọn pe ọmọ naa ti dakẹ.

‘‘Iwadii ta a ṣe lo ṣe atọna bi ọwọ ṣe ba ọkunrin kan to n jẹ Amadu Sale, tawọn eeyan ẹ tun mọ si Dan Kwairo, ẹni ọdun marundinlọgbọn, lati Abule Akar, nijọba ibilẹ Kiyawa, yii kan naa.

Amadu yii ni wọn lo fun Balaraba loyun, ti wọn si jọ gbimọ-pọ lati bo ọmọ naa mọlẹ to ba ti bi i. Awọn afurasi mejeeji ni wọn ti wa lakolo ọlọpaa bayii”.

Shiisu ṣalaye siwaju pe, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ naa, CP Emmanuel Ekot Effiom, ti paṣẹ pe ki wọn taari ẹjọ naa lọ si ẹka to n ri si iwadii iwa ọdaran ni Dutse, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ naa fun iwadii to peye. O ni ti wọn ba ti pari iwadii naa lawọn yoo foju awọn afurasi mejeeji bale-ẹjọ.

Leave a Reply