Ọrẹ timọtimọ Ayinde Barister, Buhari Ọlọtọ, jade laye

Buhari Ọlọtọ, ọkan ninu awọn ọrẹ timọtimọ gbajumọ olorin Fuji ilẹ wa to ti doloogbe, Sikiru Ayinde Barister, ti jade laye o.

Ọlọtọ to tun jẹ ọba ilu Aguda, nipinlẹ Eko, jade laye lẹni ogọrin ọdun.

Ileewosan ijọba Eko la gbọ pe o ku si ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.

Ọkan pataki ninu awọn ọrẹ imulẹ ati alatilẹyin Alaaji Sikiru Ayinde Barister ni baba yii, ipa pataki lo si ko nigba ti ọga awọn olorin Fuji naa jade laye.

Aimọye igba ni Barister ti kọrin ki i, ti wọn si ti rin irin-ajo papọ lọ si awọn ilu oyinbo kaakiri.

Leave a Reply