Ori eeyan mẹrin, ọwọ meji, ni Salisu lọọ hu nitẹ-oku n’Ijẹbu-Ode

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹ́òkúta

Ẹru ofin gbaa ti wọn ko gbọdọ ba lọwọ ọmọluabi lawọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun ba lọwọ baba ẹni ọdun marundinlọgọta (55) yii Yẹsiru Salisu. Ori eeyan mẹrin, ọwọ meji, ati agbọn (jaw) eeyan mẹta ti wọn ti ku lawọn ọlọpaa ba lọwọ rẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, l’Agọ-Iwoye, nipinlẹ Ogun.

Ojule keje, Opopona Ọdẹnusi, n’Ijẹbu-Igbo ni baba tẹsẹ kan tiẹ naa wu gelemọ yii n gbe, ṣugbọn teṣan Agọ-Iwoye lawọn to ri i pẹlu apo kan to gbe dani ti lọọ fẹjọ rẹ sun.

Awọn to sọ fọlọpaa tilẹ ṣe bi ẹru ole ni baba naa ko sapo ọhun ni, irisi rẹ to mu ifura dani lo jẹ ki wọn ko o loju pe ki lo n gbe kiri.

Ṣugbọn kaka ki Yẹsiru ṣalaye ara ẹ fawọn to beere pe ki lo wa ninu apo to gbe dani, niṣe lo ju apo naa silẹ to sa wọgbo lọ, ohun to jẹ ki wọn lọọ fọrọ naa to wọn leti ni teṣan ọlọpaa niyẹn.

DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ṣalaye pe nigba tawọn ọlọpaa debẹ ti wọn tu apo ọhun wo ni wọn ba ẹya ara eeyan wonyi nibẹ kitikiti, bi wọn ṣe bọ sinu igbo naa niyẹn ti wọn bẹrẹ si i wa ọkunrin yii.

Nigba ti wọn ri i, Salisu ṣalaye fun wọn pe itẹ oku kan to jẹ tawọn Kristẹni, to wa lagbegbe Oke-Ẹri, n’Ijẹbu-Ode loun ti hu awọn ẹya ara eeyan naa. Baba yii sọ pe ẹnikan to n jẹ Lekan Bakare lawọn jọ ge awọn ẹya ara eeyan wọnyi.

Gẹgẹ bi ọga ọlọpaa pata nipinlẹ Ogun, CP Edward Ajogun, ti paṣẹ, ẹka to n tọpinpin gidi ni wọn mu baba agbalagba yii lọ, bẹẹ ni wọn yoo wa Lekan Bakare ti wọn jọ ṣiṣẹ laabi naa jade laipẹ.

Leave a Reply