Ori ko awọn arinrin-ajo mẹsan-an yọ lọwọ awọn ajinigbe l’Ọrẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Awọn arinrin-ajo bii mẹsan-an lori ko yọ lọwọ awọn ajinigbe loju ọna marosẹ Ọrẹ si Ijẹbu Ode, lalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ko ti i ju bii iṣẹju mẹwaa pere tawọn arinrin-ajo naa gbera lati ibudokọ to wa niluu Ọrẹ, nijọba ibilẹ Odigbo, nigba tawọn Fulani ajinigbe kan deedee yọ si wọn lojiji, ti wọn si da ibọn bo ọkọ bọọsi elero mẹwaa ti wọn wa ninu rẹ.
Níbi ti awakọ bọọsi naa ti n gbiyanju ati yi ori ọkọ rẹ pada lawọn agbebọn ọhun ka wọn mọ, ti wọn si fipa ko gbogbo wọn wọnu igbo lọ.
Ninu alaye ti ọkan ninu awọn ero ọkọ ọhun to porukọ ara rẹ ni Olusọji ṣe fun wa, o ni oun lẹni akọkọ tawọn ajinigbe naa kọkọ wọ ju silẹ, nitori pe ẹnu abawọle ọkọ loun jokoo si.
Yatọ si gbogbo foonu, owo atawọn ẹru mi-in tawọn agbebọn naa gba lọwọ awọn to wa ninu ọkọ, o ni bii ẹgusi bara ni wọn lu awọn, ti wọn si tun ge ọkan ninu ika ọwọ oun bọ silẹ nibi ti wọn ti n sa oun ladaa ni gbogbo ara.
Iro ibọn awọn ọlọpaa ti awọn ajinigbe naa gbọ lo ni o ko awọn yọ pẹlu bi wọn ṣe fi awọn silẹ, ti wọn si sa lọ, kọwọ awọn agbófinró ma baa tẹ wọn.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Funmilayọ Ọdunlami, ni loju ẹsẹ tawọn ọlọpaa ilu Ọrẹ ti gba ipe nipa iṣẹlẹ naa ni wọn ti mori le ọna ibẹ, ti Ọlọrun si ran wọn lọwọ lati gba awọn arinrin-ajo mẹsan-an ti wọn ji gbe silẹ ninu igbekun awọn to ji wọn gbe.

Ọdunlami ni akitiyan awọn ọlọpaa si n tẹsiwaju lati ri awọn agbebọn naa mu, ki wọn le foju wina ofin.
Ọkan ninu awọn arinrin-ajo ọhun ti wọn sa ladaa lo ni awọn kọkọ gbe lọ si ileewosan fun itọju ki wọn too bẹrẹ irinajo wọn pada lalẹ ọjọ naa.

Leave a Reply