Ori ko awọn ọmọọlewe ati onimọto yọ bi kọntena yii ṣe ja bọ niwaju ileewe wọn l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

 

 

Bi ko ba ṣe pe aanu Ọlọrun pọ ni, igbe ẹkun ati ọfọ rẹpẹtẹ ni iba ṣẹlẹ lọjọ Ẹti, Furaidee yii, nigba ti kọntena kan ja bọ le ọkọ ayọkẹlẹ kan lori niwaju ileewe Greensprings, to wa l’Anthony, l’Ekoo.

Ọpọ awọn to ri iṣẹlẹ yii, atawọn to wo fidio kan ti wọn ju sori atẹ ayelujara nipa ẹ, ni wọn n dupẹ, ti wọn n kan saara si Ẹlẹdaa wọn pe iṣẹ iyanu lo ṣẹlẹ, bi jamba naa ko ṣẹ mu ẹmi lọ.

Akọkọ, gẹgẹ bi Ọga agba ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko, Dokita Fẹmi Oke-Ọsanyintolu, ṣ̣̣ sọ, o ni ayika tawọn akẹkọọ ileewe ọhun ti n ṣere, to tun jẹ oju ọna ti ọpọlọpọ wọn n gba lọ sile, ni iṣẹlẹ yii ti waye.

Yatọ siyẹn, o ni ibi ti kọntena ja bọ si yii, ọpọ awọn ọlọkọ lo maa n paaki kaa (car) wọn atawọn ọkọ mi-in sibẹ, awọn ẹlomi-in si maa n wa ninu awọn ọkọ naa tabi ki wọn duro ti i.

Fẹmi ṣalaye lori ikanni agbọrọkaye (tuita) ajọ ọhun pe bi ọkọ ajagbe to pọn kọntena naa sẹyin ṣe fẹẹ sọkalẹ latori biriiji Anthony, boya ẹru to pọn sẹyin lo fi i ni o, niṣe lo ja ṣooroṣo walẹ, ti kọntena ẹyin rẹ si ja bọ, ọkọ ayọkẹlẹ ọkan lara awọn olukọ ileewe naa lo ja bọ le, o run ọkọ ayọkẹlẹ funfun naa womuwomu, ṣugbọn ko seeyan kankan ninu rẹ lasiko ọhun, iyẹn ni wọn fi bọ lọwọ ewu.

Ni bayii ṣa, wọn ti waa fi katapita ajọ LASEMA wọ kọntena naa ati tirela to pọn ọn sẹyin kuro lagbegbe ọhun ko ma baa ṣediwọ fun lilọ bibọ ọkọ

Leave a Reply