Ori ko eeyan meji yọ lọwọ ajinigbe n’Idoani, lẹyin ọjọ meji ti wọn ti wa nigbekun wọn

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọkunrin kan ti wọn porukọ rẹ ni Idowu Shaba lori ti ko yọ ninu igbekun awọn to ji i gbe lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ ta a wa yii.

Ọkunrin oniṣowo koko ọhun pẹlu ọmọbinrin kan ni wọn lawọn agbebọn naa dena de, ti wọn si ji gbe lasiko ti wọn n lọ fun eto isin pataki kan to n lọ lọwọ ninu sọọsi wọn niluu Idoani, nijọba ibilẹ Ọsẹ, lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja.

Lẹyin-o-rẹyin lawọn ajinigbe ọhun kan sawọn ẹbi wọn, ti wọn si n beere fun miliọnu mẹwaa Naira gẹgẹ bii owo itusilẹ wọn.

Shaba ni wọn lo dibọn bii ẹni ti oorun ti wọ lara pẹlu bo ṣe takaaka, to si n han-an-run ninu igbo ti wọn ko wọn lọ.

Eyi lo fọkan awọn ajinigbe to n ṣọ wọn balẹ tawọn naa fi fẹyin lelẹ, ti wọn si sun lọ fọnfọn gẹgẹ bi owe awọn agba to ni “oorun ni i gba tọwọ ọmọde.”

Kia lọmọkunrin naa ti fo dide pẹlu igboya, to si yara ki ada ati ibọn awọn ajinigbe to n ṣọ wọn mọlẹ, eyi to fi doju ija kọ wọn ko le raaye gba ọmọbinrin ti wọn ji gbe pẹlu rẹ lọwọ wọn.

A gbọ pe Shaba fi awọn nnkan ija to ja gba lọwọ awọn janduku ọhun pa lara wọn ki oun ati ẹnikeji rẹ too lanfaani ati sa mọ wọn lọwọ.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abilekọ Funmi Ọdunlami, ni loootọ loun gbọ pe awọn eeyan ọhun sa mọ awọn ajinigbe lọwọ, ṣugbọn oun ko ri i gbọ lati ẹnu wọn pe wọn pa ẹnikẹni.

 

Leave a Reply