Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
O kere tan, eeyan mẹrin ni ori ko yọ lọwọ iku ojiji lagbegbe Ọffa Garage, niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, lasiko ti ajagbe to gbe kọntena kan ṣubu lu ọkọ ayọkẹlẹ Mitsubishi kan ti awọn eeyan ọhun wa ninu ẹ.
ALAROYE gbọ pe arabinrin kan ati awọn ọmọ rẹ mẹta lo wa ninu ọkọ ti ajagbe wo lu ọhun, ṣugbọn ajọ panapana ipinlẹ Kwara, ajọ ẹṣọ alaabo oju popo ati ileeṣẹ ọlọpaa lo doola ẹmi awọn mẹrẹẹrin lọwọ iku ojiji pẹlu bi wọn ti gbiyanju lati yọ wọn kuro ninu ọkọ Mitsubishi naa.
Adari ajọ panapana nipinlẹ Kwara, Ọmọọba John Falade, ati adari ẹka to n ri si iṣẹlẹ pajawiri lajọ KWARTMA, Saidu Kannike, toun naa wa lara awọn to doola ẹmi wọn fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin. Wọn ni ko sẹni to ku, ṣugbọn awọn to fara pa n gba itọju lọwọ nileewosan. Bakan naa lo sọ pe irọ ni iroyin ti awọn kan n gbe kiri pe ajọ ẹṣọ alaabo asọbode lo n le ajagbe ọhun to fi sare asapajude to fi ni ijamba, o ni irọ to jinna soootọ ni.
Wọn ti waa rọ awọn awakọ pe ki wọn maa wa ni toju-tiyẹ nigba ti wọn ba n wakọ loju popo, ki wọn si maa bọwọ fun ofin irinna nigba gbogbo, ki ijamba le dinku lawọn oju popo nilẹ yii.