Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ori lo ko eeyan mẹta yọ lọwọ iku ojiji lọjọ Ẹti, Furaidee, ọṣẹ yii, lakooko ti ọkọ akero elero mẹrindinlogun kan gbina lagbegbe Challenge, niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara.
ALAROYE gbọ pe lati ipinlẹ Eko ni ọkọ ero ọhun ti n bọ, to si n ja awọn ero inu rẹ diẹ diẹ nigba to wọ ilu Ilọrin. Eeyan mẹta lo ku sinu ọkọ naa ko too di pe o sọ ijanu rẹ nu, to n sare lọ, lo ba gbina. Awọn ero mẹta to wa ninu ọkọ naa mori bọ lọwọ iku, sugbọn ọkọ naa jona raurau ko too di pe ajọ panapana de sibi iṣẹlẹ ọhun.
Agbẹnusọ ajọ panapana nipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Hassan Hakeem Adekunle, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni wọn o tete kan si ajọ panapana lo fa a ti ọkọ ọhun fi jona raurau. Adari agba fajọ naa nipinlẹ Kwara ti waa rọ gbogbo olugbe ipinlẹ naa lati tete maa kan si ajọ panapana nigbakuugba ti ina ba n ṣọsẹ lati le dena pipadanu ẹmi ati dukia wọn.
Ibrahim Alagunmu, Ilọrin