Ori ko oludije gomina ipinlẹ Ọyọ yọ lọwọ awọn agbanipa

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ẹlẹkọ ọrun polowo iku lọ sile Sẹnetọ Teslim Fọlarin, oludije funpo gomina lorukọ ẹgbẹ oṣelu Onigbaalẹ, APC, ṣugbọn ori ko ọkunrin naa yọ lọwọ iku ojiji pẹlu bi awọn agbanipa ọhun ko ṣe ba a nile.

Fọlarin ni Mọgaji agboole wọn l’Ọja’gbo, n’Ibadan, nitori ipo to di mu lagboole wọn yii lo si ṣe pinnu lati ṣepade pẹlu awọn ọmọ agboole naa laago mẹjọ alẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹta, ọdun 2023 yii.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, ni nnkan bii aago mẹjọ kọja iṣẹju mẹwaa lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, lasiko to yẹ ki wọn ti maa ṣepade ọhun lọwọ lawọn agbanipa to fẹẹ gbẹmi Fọlarin ṣigun wọnu aafin Ọja’gbo, ninu gbọngan nla ti wọn ti fẹẹ ṣepade ọhun tibọntibọn.

Ọpọ awọn to n duro de oludije funpo gomina lorukọ ẹgbẹ oṣelu APC yii ni gbọngan ipade naa ni wọn fara pa yanna-yanna nibi ti kaluku wọn ti n sa asala fẹmi-in ẹ.

Ọkan ninu awọn tiṣẹlẹ yii ṣoju wọn ṣalaye pe “awọn agbanipa yẹn da aṣọ dudu boju, ọkọ Toyota Hilux bii mẹwaa ti wọn ti fi nnkan di nọmba idanimọ wọn ni wọn gbe wa. Bi wọn ṣe de ni wọn n yinbọn soke, ti wọn si n pariwo pe “Tẹsi lo kan! Iku lo kan ẹ”!

Ibọn ti wọn n yin soke bi wọn ṣe n foju wa Fọlarin kiri ni wọn fi tu gbogbo wa ka.

‘‘Ọpọ ninu awa ti a n duro de e lo si fara pa nibi ta a ti n sa asala fun ẹmi wa, ṣugbọn a dupẹ pe Ọlọrun ko fi ẹmi ẹnikankan ninu wa le wọn lọwọ”.

Nigba to n bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ yii, Akọweeroyin Sẹnetọ Fọlarin, Ọgbẹni YSO Ọlaniyi, sọ pe “wọn ro pe Oloye maa ti wa nibi ti wọn ti fẹẹ ba wọn ṣepade yẹn ni, wọn o mọ pe ibi ti wọn ti n ṣeto kan lọwọ lori redio ni wọn wa lasiko yẹn. Eto ti wọn n ṣe yẹn lo da wọn duro ti wọn ko ṣe ti i de sibi ipade yẹn lasiko ti awọn apaayan yẹn ṣigun de.

O waa rọ ọga ileeṣẹ ọlọpaa lati pese eto aabo to peye fun Fọlarin, ki awọn to n lepa ẹmi ẹ ma baa ri i pa.

Leave a Reply