Ori ọrẹ iyawo mi la ta fun Ọmọ Baalẹ lẹgbẹrun lọna aadọrin Naira-Ọladimeji

Jọkẹ Amọri

Tọkọ-tiyawo kan, Kẹhinde Ọladimeji ati Adejumọkẹ Raji, ti jẹwọ bi wọn ṣe ri ẹya ara eeyan tawọn agbofinro ka mọ wọn lọwọ lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja yii.

Nigba ti awọn ọlọpaa n ṣafihan wọn lolu ileesẹ wọn to wa ni Eleweran, niluu Abẹokuta, ni Kẹhinde, ẹni ọdun mẹtalelogoji, ṣalaye pe ọrẹ iyawo oun ni ẹni ti wọn ba ẹya ara rẹ ninu ile awọn, ati pe iyawo oun lo pa obinrin naa, to si kun un si wẹwẹ.

O ni, ‘‘Ọjọ kan wa ti iyawo mi pe ọre rẹ wa pe ko waa ki oun. Ọjọ Iṣegun kan bayii lo kọkọ wa, o wa, o si pada lọ lọjọ naa.

‘‘Ṣugbọn nigba ti yoo tun pada wa, Ọjọbọ, Tọsidee, lọjọ to pada wa yii bọ si. Iyawo mi lo se Indomine ati ẹyin fun ọrẹ rẹ yii, tiyẹn jẹ ẹ, to si bọ sileewẹ, to loun n lọọ wẹ. Nigba to di pe ilẹ n ṣu ni mo bi iyawo mi pe ṣe ọre rẹ ko ni i lọ sile mọ ni, o waa sọ fun mi pe ọmọbinrin naa ni o ti rẹ oun, pe oun ni lati sinmi diẹ ki oun too maa lọ.

‘‘Ni gbogbo igba yẹn, ẹyinkule lemi jokoo si, mi o si ninu ile pẹlu wọn, ṣugbon nigba ti mo fi maa pada wọle, mo ri i pe iyawo mi ti pa ọrẹ rẹ yii, o si ti kun un wẹlẹwẹlẹ, nigba ti mo si beere idi to fi pa a, o lo ti ṣẹ oun nigba kan ri.

‘‘Lasiko yẹn lemi wa n ba ọrẹ mi kan sọrọ lori foonu, Ọmọ Baalẹ lorukọ re, Ibadan lo si n gbe. Oun lo waa sọ fun mi pe oun nilo ori eeyan, pe ti mo ba le ba oun wa a. Ọrọ ti a n sọ lori foonu yii ni iyawo mi gbọ to fi ni ti ọre mi yii ba le sanwo, oun maa ta ori ọrẹ oun yii fun un. Mo beere pe eelo lo feẹ gba, o si ni ẹgbẹrun lọna aadọrin Naira (70, 000) loun maa gba.

‘‘Ọkunrin yii ni iyawo mi ta ori ọrẹ rẹ yii fun, to si gba ẹgbẹrun lọna aadọrin Naira lọwọ rẹ.’’

Ṣugbọn iyawo Kẹhinde, Adejumọkẹ Raji sọ pe irọ nla ni ọkọ oun pa mọ oun. O ni oun ko pa ọrẹ oun kankan, ati pe ọrẹ ọkọ oun kan to n jẹ Micheal lo gbe apo ṣakaṣaka kan wa fun awọn, awọn ko si tete mọ ohun to wa nibẹ. O ni lẹyin ọjọ kẹta lawọn too mọ pe ẹya ara eeyan lo wa ninu apo naa.

Tẹ o ba gbagbe, Satide ọse to kọja ni Baalẹ Leme mu ẹsun awọn tọkọ-tiyawo naa lọ si agọ ọlọpaa to wa ni  Kemta pe ọkan ninu awọn alajọgbele tọkọ-tiyawo yii lo waa sọ foun pe awọn n gbọ oorun buruku kan to n jade lati inu ile awọn eeyan naa. Baalẹ paapaa ko fọrọ ọhun jafira to fi lọọ sọ fawọn ọlọpaa. Awọn agbofinro ni wọn ya bo ile naa to wa ni Ojule Kejilelaaadọrin, MKO Abiọla Way, to wa niluu Abẹokuta, gẹgẹ bi Oyeyẹmi ṣe sọ.

Ibẹ ni wọn ti ba ike kan ninu ile wọn to jẹ pe ẹya ara eeyan loriṣiiriṣii lo wa nibẹ. Eyi lo mu kawọn ọlọpaa fọwọ ofin mu wọn.

Alukoro ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi, ni iwadii ṣi n tesiwaju, ati pe ni kete tiwadii ba ti pari ni wọn yoo foju ba ile ẹjọ.

Leave a Reply