Ori Wasaapu ni gomina Kwara ti n ṣejọba tiẹ bayii-PDP

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), nipinlẹ Kwara, ti fẹsun kan Gomina ipinlẹ naa, Abdulrahman Abdulrazaq, pe ṣe lo n ṣe ijọba Kwara nipasẹ lilo atẹjiṣẹ ori ayelujara Wasaapu, to si pa gbogbo awọn iṣẹ akanṣe opopona to n ṣe lọwọ ti gẹgẹ bii aṣọ to ti gbo.

Ninu atẹjade kan ti Akọwe to n gbe iroyin ẹgbẹ naa jade, Ọgbẹni Oluṣẹgun Adewara, fi sita to tẹ ALAROYE lọwọ lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, lo ti ni ki gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrazaq, lori bo ṣe pa gbogbo awọn iṣẹ akanṣe opopona to n lọ nipinlẹ naa ti, to si n ba ohun ti ko kan an lọwọ-lẹṣẹ kiri, paapaa nipa opopona to n lọ lọwọ ni Eko ati Calabar, to pa awọn eeyan Kwara to dibo fun un ti.

O tẹsiwaju pe ohun iyalẹnu ni ọrọ naa jẹ fun ẹgbẹ oṣelu PDP, pẹlu bi ọrọ ipinlẹ Kwara ko ṣe jẹ gomina logun mọ, to si jẹ pe iṣẹ ijọba apapọ lo n wa mọya kiri.

O ni, “gomina wa ti ko lọ si ilu Abuja tipẹ, to si n ṣe ijọba Kwara latori atẹjiṣẹ lori Wasaapu, ti yoo si maa ya awọn ayederu fọto nigbakuugba to ba wa sile.

“Eleyii ko le jẹ itẹwọgba mọ rara, nitori pe Abdulrasaq ti sọ ipinlẹ Kwara di akurẹtẹ nibi ti ko ti si eto aabo mọ, ti ijinigbe n peleke si i lojoojumọ. Bakan ni ẹka eto ilera ati eto ẹkọ ti dẹnukọlẹ, tawọn akẹkọọ si n kẹkọọ labẹ igi gẹgẹ bii iroyin ti ileeṣẹ BBC gbe jade nipa ileewe alakọọbẹrẹ Kánkán LGEA, to wa nijọba ibilẹ Asà, nipinlẹ naa.

Ẹgbẹ oṣelu PDP ti waa kesi Gomina Abdulrasaq, ko tete pada wale lati ilu Abuja to lọọ joko si, ko waa lo gbogbo agbara rẹ fun idagbasoke ati igbaye-gbadun awọn eeyan ipinlẹ Kwara, ko si lo anfaani alaga igbimọ gomina to jẹ lati fi kore wale.

 

Leave a Reply