Orilẹ-ede Yoruba: Awọn eeyan wọde l’Abẹokuta

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Arọni o wale Onikoyi o sinmi ogun lawọn to n beere fun Orilẹ-ede Yoruba n wi, iyẹn naa lo si gbe wọn jade layajọ ‘June 12’, l’Abẹokuta.

Orin kan naa ti wọn n kọ bi wọn ṣe n kiri igboro ilu naa ko ju pe awọn fẹẹ kuro ni Naijiria, Orilẹ-ede Yoruba lawọn fẹ.

Mọto rẹpẹtẹ ati ọkada pupọ lawọn oluwọde naa fi n polongo kiri awọn agbegbe bii Ibara ati Ṣapọn. Koda, wọn gba iwaju ọgba ẹwọn ati ileefowopamọ ilẹ wa kọja n’Ibara, wọn ko sọ nnkan meji ju pe awọn n fẹ ilẹ Olominira Yoruba lọ.

Bo tilẹ jẹ pe iwọde naa ko mu ija wa, nigba ti wọn de iwaju ọgba ẹwọn Ibara, awọn agbofinro to wa nibẹ ni ki wọn maa lọ, ki wọn ma jo de iwaju awọn rara.

Ọrọ naa dija nibudokọ Lagos Garage, n’Ijẹbu-Ode, nigba ti awọn ọmọọta gba iwọde naa mọ awọn ti wọn n ṣe e lọwọ, ti wọn si bẹrẹ si i yinbọn.

Leave a Reply