Orileede Amẹrika koro oju si iwa janduku, ẹlẹyamẹya to waye lasiko ibo gomina ati t’aṣofin

Monisọla Saka

Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹta, ọdun yii, ni awọn aṣoju ilẹ Amẹrika lorileede yii, Memeber of US Diplomatic Mission,  Nigeria, leri pe awọn yoo gbẹsẹ le ọrọ fisa gbigba atawọn nnkan mi-in lori awọn eeyan to ba han pe wọn lọwọ ninu bi wọn ṣe halẹ mọ awọn oludibo, ti wọn ko si jẹ ki awọn eeyan naa ṣe ojuṣe wọn lasiko ibo gomina ati ti ileegbimọ aṣofin to waye lọjọ Kejidinlogun, oṣu Keji, ọdun yii, paapaa ju lọ nipinlẹ Eko, Kano atawọn ipinlẹ mi-in.

Ninu atẹjade ti ileeṣẹ Amẹrika ni Naijiria yii fi sori ẹrọ ayelujara wọn, ni wọn ti bu ẹnu atẹ lu ọrọ ẹlẹyamẹya ti wọn lo ṣaaju eto idibo, lasiko rẹ ati lẹyin ti wọn dibo gomina tan nipinlẹ Eko.

Wọn sọ pe, ‘Orileede Naijiria ṣeto abala keji idibo wọn, iyẹn eto idibo gomina ati ti ileegbimọ aṣofin lọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹta, ọdun yii. Orileede Amẹrika kọminu si bi gbogbo eto ibo naa ṣe lọ pẹlu jagidijagan, ti wọn si n halẹ mọ awọn oludibo, ti wọn ko si fun wọn lanfaani lati ṣe ojuṣe wọn ni awọn ipinlẹ bii Eko, Kano ati awọn ipinlẹ mi-in.

‘‘Aṣoju ilẹ Amẹrika ni Naijiria wa ninu awọn to wo bi ibo naa ṣe lọ si, bẹẹ la si ri gbogbo awọn iwa aitọ wọnyi lojukoroju. Lilo ọrọ ẹlẹyamẹya ki eto idibo naa too waye ati lasiko idibo gomina niluu Eko jẹ ohun to ka ni laya.

‘‘A gboriyin fun gbogbo awọn to kopa ninu eto naa lorileede yii, awọn aṣaaju ẹsin ati awọn adari agbegbe, awọn ọdọ atawọn ọmọ orileede yii ti wọn yan lati koro oju si iru igbesẹ yii, ati lati sọrọ lodi si awọn ọrọ adogun silẹ, eyi to fidi ifaraji Naijiria ati ọwọ ti wọn ni fun ijọba awa-ara-wa han.

A pe awọn alaṣe orileede Naijiria ati gbogbo awọn tọrọ kan lati ri i pe wọn gbe igbesẹ to yẹ labẹ ofin lati ri i pe awọn to n halẹ mọ awọn oludibo lasiko idibo atawọn ti wọn ko jẹ ki awọn eeyan ṣe ojuṣe wọn lasiko idibo naa ko lọ lasan.

Bakan naa ni orileede Amẹrika yoo gbe igbesẹ to ba yẹ ninu eyi ti fifofin de awọn ti wọn ba lọwọ ninu iwa yii tabi ti wọn ṣe atilẹyin fun un atawọn ti wọn fẹẹ doju ijọba awa-ara-wa bolẹ lati gba iwe aṣẹ lati rin irinajo lọ si Amẹrika (visa).

‘‘Bakan naa ni a si tun n laago rẹ pe ki ẹnikẹni to ba ni ẹdun ọkan tabi ẹsun kankan lori eto idibo to lọ naa ki wọn gba ọna to tọ labẹ ofin, eyi ti ẹnikẹni ko gbọdọ dabuu ọna wọn lori rẹ.

Bakan naa la n pe awọn ọmọ Naijiria lati ṣisẹ papọ, bi wọn ti n n gbiyanju lati so okun eto ijọba awa-ara-wa mu dain-dain lorileede yii’’.

 

Leave a Reply