Monisọla Saka
Igbakeji Aarẹ ilẹ wa nigba kan, to tun jẹ oludije sipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP lasiko eto idibo ọdun to lọ, Alaaji Atiku Abubakar, ti ni ko si nnkan kan bayii to n ṣiṣẹ, ti itẹsiwaju si de ba, labẹ iṣejọba Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu.
Ni iṣami ọdun kan Tinubu gẹgẹ bii Aarẹ orilẹ-ede yii, ni Atiku fi atẹjade yii sita lati sọrọ nipa iṣejọba Tinubu lati ọdun kan sẹyin.
Atiku ni ko si itẹsiwaju tabi idagbasoke kan bayii, ati pe ileri Aarẹ lati tun eto ọrọ-aje ṣe, ko si mu idagbasoke ba ilẹ Naijiria latara ipese iṣẹ, ounjẹ lọpọ yanturu, ni ko mu ṣẹ.
“Loṣu mejila geerege, gbogbo ileri Tinubu lati mu idagbasoke ba eto ọrọ aje wa ati lati fopin si iṣẹ ati oṣi ni ko i ti i mu ṣẹ.
Gbogbo igbesẹ rẹ lo ti fi ba eto ọrọ-aje alabọọde Naijiria jẹ, niṣe lo n buru si i ju bo ṣe wa lọdun kan sẹyin lọ.
Lai si ani-ani, gbogbo awọn kudiẹ-kudiẹ to n mu ki eto ọrọ aje wa lọ silẹ bii airiṣẹ-ṣe, oṣi ati iṣẹ, ati awọn aburu yooku to gogò lasiko ijọba Buhari tubọ waa ga si i ni.
Tinubu ti sọ ireti awọn araalu somi, leyii to ta ko ‘Ireti Isọdọtun’ to pe eto iṣejọba rẹ, nitori aburu to ba eto ọrọ-aje Naijiria tubọ n pọ si i ni”.
Atiku ni gbogbo aba ti Tinubu n mu wa lo n ṣakoba fun ilẹ Naijiria, nitori ko si ipalẹmọ ki wọn too bẹrẹ iru awọn eto bẹẹ, bẹẹ ni ko mọ ọna to yẹ lati gbe e gba. O ni eyi-jẹ eyi-o-jẹ lo n fi ijọba rẹ ṣe, nitori ko si eto kan gboogi tabi ibi ti iru eto bẹẹ n dori kọ.
“Dipo ki wọn tun ilu ṣe, wọn tubọ n sọ awọn talaka di oloṣi si i ni, ti awọn olowo gan-an si n lu gbese. Wọn ko da ẹnikẹni si. Awọn ọmọ Naijiria to jẹ pe awọn alaini lo pọ ju ninu wọn ni igbe aye wọn ti tubọ le si i, ti wọn si n gbe ninu inira”.
O ni lara ifasẹyin ti Tinubu tun ko ba eto ọrọ aje wa ni bo ṣe lori laya lati yọ owo iranwọ epo bẹntiroolu, to si tun la owo-ori sisan bọ awọn eeyan lọrun, amọ ti ko loju aanu to lati ṣafikun owo-oṣu to kere ju, tabi eto ti yoo mu adinku ba inawo ati wahala fun mọlẹbi awọn oṣiṣẹ.
Atiku tẹsiwaju pe nitori iṣejọba lile Tinubu ti ko faaye gba awọn onileeṣẹ ati olokoowo ni pupọ wọn fi fi ilẹ Naijiria silẹ, ti awọn eeyan to le ni ogun ẹgbẹrun si padanu iṣẹ wọn.
Nigba to mẹnuba ọrọ ipaarọ owo ilẹ okeere, o ni ofin tuntun ti Tinubu ṣe lori ẹ ko ti i nipa rere kan lori okoowo ati eto ọrọ-aje Naijiria. Gbogbo afẹfẹyẹyẹ ati fọto to ni awọn oluranlọwọ ẹ lori eto iroyin n gbe kiri nipa biba awọn ilẹ okeere dowo-pọ, lo sọ pe ko tori ẹ mu awọn to le da ileeṣẹ silẹ wọlu.
“Pẹlu gbogbo ọgbọn tẹ ẹ da si ọrọ owo, nnkan ko ṣai maa gbẹnu soke. A ko le fi ẹmi imoore kankan han si ijọba Tinubu, owo Naira ti waa ja lọ silẹ gidi gan-an lẹgbẹẹ dọla, eyi ti a ko riru ẹ ri ninu itan Naijiria”.
O ni akoko n lọ fun ijọba Tinubu, o si gbọdọ ṣe kia lati ṣatunṣe si eto ọrọ-aje ilẹ yii, nitori ijọba eyi-jẹ eyi-o-jẹ ti wọn n ṣe n jẹ kawọn eeyan maa ṣiye meji lori bi ijọba rẹ ṣe wa ni imurasilẹ to, ati ipa rẹ lati mu amugbooro ba eto ọrọ aje wa.