Faith Adebọla, Eko
Aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu APC, Bọla Hamed Tinubu, ti sọ pe orileede Naijiria nilo eeyan to ni igboya, to si ni iriri bii toun lati dari rẹ. O ni iru ẹni bẹẹ ni yoo mu ayipada ta a nilo wa, ti yoo si le pa owo ti yoo gbe Naijiria goke agba wọle.
L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, lo sọrọ naa lasiko ipade ọlọjọ kan ti awọn ọmọ ileegbimọ aṣofin Eko ṣe fun awọn olori aṣofin ati igbakeji wọn to wa nipo bayii atawọn to ti wa nibẹ tẹlẹ ti wọn wa lati ipinlẹ ti oṣelu APC n dari.
Aṣiwaju ni Ọlọrun fi awọn eeyan to kun oju oṣuwọn daadaa ti wọn le mu ayipada tootọ ba orileede yii jinki wa, ṣugbọn akiyesi gidi gbọdọ wa lori bi awọn to fẹẹ dupo naa ṣe kun oju oṣuwọn to lati dari.
Tinubu, ẹni to ṣapejuwe ara rẹ gẹgẹ bii ẹni kan ti Naijiria nilo bayii lati maa tukọ itẹsiwaju orileede yii ni, ‘‘Naijiria nilo mi, gẹgẹ bi emi naa ṣe nilo Naijiria. Naijiria nilo onigboya to le mu ayipada kiakia ba bi owo ṣe n wọle, emi si ni ẹni to ni igboya ti wọn nilo.
‘‘Mo dagba sinu ki eeyan ni igboya ni, eleyii si ti n ṣiṣẹ fun mi lọpọ igba, eleyii naa ni mo si fẹẹ ṣamulo lati ṣe aarẹ Naijiria.
O fi kun un pe idagbasoke to ya kiakia fun orileede wa ni i ṣe pẹlu rironu nipa rẹ ati mimu un wa si iṣe. ‘Mo si ti ṣetan lati ṣe iru eleyii leẹkan si i, nitori mo jẹ eeyan to maa n ronu, to si maa n mu un lọ sinu iṣe.’
Ipade naa ti wọn pe akori rẹ ni: Awọn aṣofin, bi igba ṣe n yipada ati irinajo ijọba awa-ara-wa ni Naijiria’ (The Legislature, Changing times and Nigeria’s Democratic Journey), lo waye ni ikẹja. Ọpọ awọn olukopa naa lo fi tẹrin-tọyaya ki Tiinubu kaabọ saarin wọn, ti wọn si kọrin fun un pe lori ipinnu rẹ lati dupo aarẹ naa ni awọn duro le lori.