Orileede Nijee lọwọ ti tẹ Maina, ọkunrin to ko owo awọn oṣiṣẹ-fẹyinti je

Irọlẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni ọwọ awọn ọlọpaa ọtelẹmuyẹileeṣẹ EFCC pẹlu ifọwọsowọpọ awọn ọtelẹmuyẹ ọlọpaa orileede Nijee,  tẹ Abdulrasheed Maina, alaga  ileeṣẹ to n mojuto atunto ọrọ owo-osu awọn oṣiṣẹ-fẹyinti nilẹ wa , (Pension Reform Task  Team), to sa lọ. Orileede Nijee ni wọn ti mu ọkunrin to sa lọ naa lẹyin ti ile-ẹjọ gba oniduuro rẹ ninu oṣu kẹsan-an, ọdun yii.

Ẹsun mejila ọtọọtọ ni wọn ka si ọkunrin yii ati ileeṣẹ kan lọrun, eyi ti i ṣe kiko owo ilẹ wa pamọ soke okun. Ileeṣẹ yii la gbọ pe ọkunrin naa lo to fi ko owo to to biliọnu meji naira (2billion) to ko jẹ lọ silẹ okeere. Lara owo naa lo si tun fi ra ile nla nla  bii mẹtalelogun siluu Abuja.

Latigba ti aṣiri owo buruku ti ọkunrin yii ko jẹ ti tu sita lo ti sa lọ, ti wọn si n wa a, ko too di pe ọwọ tẹ ẹ lẹyin ọdun mẹrin to ti sa lọ. Latigba naa ni lọrọ rẹ ti wa nile-ejọ. Ọkan ninu awọn minisita ilẹ wa, Ali Ndume lo ṣoniduuro fun ọkunrin yii nigba to fara han nile-ejọ gbẹyin lọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹsan-an, ọdun yii.

Ṣugbọn latigba naa ni ọkunrin yii ti sa lọ, ti ko si yọju sile-ẹjọ fun igbẹjọ mọ. Eyi lo mu ki Adajọ Okon Abang ti ile-ẹjọ giga niluu Abuja paṣẹ pe ki wọn lọọ fọwọ ofin mu Sẹnetọ Ali Ndume to ṣe oniduuro fun un lọjọ Aje, Mọnde, ọse yii. Ṣugbọn ile-ẹjọ pada tu ọkunrin naa silẹ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja.

Eyi waye pẹlu bi ọkunrin naa ṣe pe ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun ta ko bi wọn ṣe mu un nitori wọn ko ri ẹni to soniduuro fun, ti wọn si fẹẹ sọ ọ sẹwọn. N ni adajọ ba ni ki wọn tu u silẹ ki wọn fi gbọ ẹjọ to pe naa.

Ko pẹ rara ti olobo fi ta ileeṣẹ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ati ṣiṣe owo ilu mọku mọku, EFCC, pe orileede Nijee ni ọkunrin naa sa lọ.   Ni wọn ba ke si awọn ileesẹ eto aabo ati ọtelẹmuyẹ orileede naa. Awọn EFCCati awọn agbofinro Nijee yii ni wọn si jọ ṣiṣẹ papọ ti ọwọ wọn fi tẹ Maina lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.

Bẹ o ba gbagbe, ọjọ keji, oṣu kẹwaa, ọdun to kọja, ni ileeṣẹ  ọtẹlẹmuyẹ kede pe awọn ti mu Maina yii niluu Abuja pẹlu ọmọ rẹ ọkunrin lẹyin ọdun mẹrin ti wọn ti n wa a. Ile bii mẹtalelogun ni wọn ki mọ ọkunrin yii nikan lọrun, bẹẹ ni wọn fẹsun ikowojẹ biliọnu meji to jẹ owo awọn oṣiṣẹ-fẹyinti kan an, eyi to mu ki wọn le e kuro lẹnu iṣẹ ijọba lọdun 2013.

Leave a Reply