Ọrọ baba atọmọ lọrọ emi ati Ọọni Ifẹ, mo ti pe wọn lori foonu-Sunday Igboho

Akikanju ọmọ ilẹ Yoruba nni, Sunday Igboho, ti sọ pe ki i ṣe pe oun ni i lọkan lati ri Ọọni Ileefẹ, Ọba Ogunwusi fin, o ni oun n fi ọrọ naa ta wọn ji ni. O ni ọrọ naa ka oun lara ni, nitori oun wọnu igbo, oun si mọ ohun to n ṣẹlẹ nibẹ. Bẹẹ lo ni ki i ṣe Ọba Ogunwusi nikan loun doju ọrọ naa kọ, o ni gbogbo awọn agbagbga ilẹ Yoruba loun n ba wi lati fi ta wọn ji si ni. Bakan naa lo fi kun un pe ọrọ baba atọmọ ni, awọn si ti yanju rẹ. 

Igboho ni oun ti bẹ Kabiyesi, awọn si ti jọ ṣalaye ọrọ funra awọn nitori nilẹ Yoruba, ẹnu ọmọ ko gba iya padi mọ, ṣugbọn bi ọrọ naa ṣe ka oun lara, to si n dun oun loun fi sọrọ ti oun sọ yii. O ni bi awọn Fulani ajinigbe ṣe n paayan, ti wọn si n ji awọn eeyan gbe lo ka oun lara.

Igboho ni, ‘‘Ẹ wo bi wọn ṣe pa awọn eeyan ni Ibarapa. Ko too kan Aborode, ẹ woye eeyan ti wọn ti paa danu. Adugbo Ibarapa yii naa ni wọn ti pa Ọkọ Oloyun. Ẹ wo bi wọn ṣe pa Dokita Aborode, mọlẹbi mi ni Aborode, ila kan naa lo jọ wa loju wa. Bakan naa ni wọn pa odidi ọba  Ifọn, awọn ọba ilẹ wa ko si gbe igbesẹ kankan lori rẹ.

‘‘Gbogbo ẹyin ti ẹ jẹ baba wa, ti ẹ jẹ booda wa, ti ẹ n bu mi, o yẹ ki ẹjẹ le run lara yin to ba jẹ pe ojulowo ọmọ Yoruba tootọ niyin, ẹ saanu Yoruba, alaafia ko si nilẹ Yoruba, won kan n pa wa kaakiri, wọn n ji wa gbe, wọn n gbowo lori wa, awọn ohun to n ka mi lara niyi. Awọn ti wọn si n ṣejọba le wa lori ko raaye tiwa, wọn kan n jaye ori wọn kiri ni. Bi wọn ṣe n lọ siluu oyinbo ni wọn n lọ si Dubai, awọn to sun mọ wọn nikan lo ri anfaani wọn jẹ.

‘‘Awọn ọmọ kawe, wọn ko ri iṣẹ, wọn n ṣe ọkada, wọn n wa Maruwa, awọn obinrin n ṣiṣẹ aṣẹwo kiri. Gbogbo ohun to n dun wa niyẹn.

‘‘Wọn ni mo sọrọ si baba wa, Ọọni Ileefẹ, mo ti pe baba wa Ọọni ati Olugbọn, Emi ati baba wa Ọọni ti sọrọ lori foonu. Eeyan ko ni i bu ọba lẹyin ko de iwaju rẹ ko ni oun bu u. Ninu aṣa Yoruba, ọmọ Yoruba gidi ko le sọ bẹẹ. Bi ọrọ yii ṣe n ka mi lara ni mo fi sọ ọ. Mi o si gba kọbọ lọwọ ẹnikẹni, mo le fi Ọlọrun ṣẹri.    

‘‘Gbogbo ohun ti mo n ṣe ni pe ki awọn baba wa naa le mọ pe awọn ni awọn ọmọ akin, ki awọn Fulani naa le mọ pe awọn ọmọ akin wa ni ilẹ Yoruba.

‘‘Ki i ṣe emi nikan ni, aimọye awọn ọmọ Yoruba kaakiri ti wọn tiẹ lagbara daada, ṣugbọn ẹru n ba onikaluku wọn naa ni. Ṣugbọn ẹni kan naa lo ma kọkọ jade.

‘‘Mo bẹ wa pe ka fi ọwọ sọwọpọ, ka ma si ṣe ditẹ ara wa, ki awa naa si ji giri lati ja ija yii to fi jẹ pe awọn ọmọ tiwa naa to n bọ lẹyin ko ni i di oloṣo, ti wọn ko si ni i maa gun ọkada kiri lọjọ ọla. O yẹ ki awa naa fi ipa rere lele.’’

Leave a Reply