Ọrọ bẹyin yọ! Idi ti Buhari fi sa fawọn aṣofin ree o

Lati bii oṣu mẹta si asiko ti a wa yii ni iroyin buruku kan ti tun jade sita, iroyin naa ko daa rara. Iroyin pe Aarẹ Muhamamdu Buhari kọ lo n ṣejọba ni, awọn ti wọn gbe iroyin naa kiri sọ pe “Buhari ti ku tipẹ, Jubril lati Sudan lo n ṣejọba!” Akọkọ ti iroyin naa yoo jade kọ niyi o. O ti kọkọ jade lati igba ti ara Aarẹ wa yii ko ti ya, ti ọkunrin ọmọ Ibo kan to n ṣe olori ẹgbẹ awọn Biafra, iyẹn Nnamdi Kanu, to sọ pe dandan ni ki Ibo kuro lara Naijiria, ti gbe ọrọ naa jade. Nigba naa, ariwo ọrọ naa kari aye gan-an, ti wọn saa n sọ pe Buhari ti ku, ko too waa di pe ọrọ naa lọ silẹ nigba to ya, lasiko ti awọn araalu bẹrẹ si i ri Buhari nita. Ṣugbọn lẹnu ọjọ mẹta yii ti awọn eeyan ko tun ri Buhari nita mọ, ti awọn ohun aburu si n ṣẹlẹ ni Naijiria, tawọn eeyan n ro pe o yẹ ki Buhari sọrọ ti ko sọ ọ, iroyin naa tun dide wuya, awọn eeyan si n sọ pe ṣebi awọn ti sọ tẹle pe Buhari kọ lo n ṣejọba.

Bi awọn kan ti n sọ bayii, bẹẹ lawọn kan n gbeja Buhari, ti wọn n sọ pe awọn ọmẹ ẹgbẹ PDP, ati awọn ọta Buhari mi-in, ni wọn n fi ete lu ara wọn lasan, isọkusọ ni wọn n sọ. Ṣugbọn Buhari ko ran awọn ti wọn n gbeja rẹ yii naa lọwọ, nitori ki i fẹẹ jade rara sibi ti awọn araalu yoo ti ri i, bẹẹ ni ki i sọrọ soke ki awọn eeyan gbọ, agaga nigba ti ohun ti ko dara kan ba n ṣẹlẹ laarin ilu. Ẹẹkọọkan ti oun ba fẹẹ sọrọ, awọn ọrọ to maa n sọ ki i bọ soju ọna, nitori ẹ lo ṣe jẹ nigbakigba to ba fẹẹ sọrọ ni gbangba, wọn yoo kọ ohun ti yoo sọ fun un ni. Ṣugbọn pẹlu ẹ naa, pẹlu pe wọn kọ ọrọ ti yoo ka fun un ni yii, ọpọ igba lo jẹ nnkan mi-in ni yoo maa ka ninu iwe ti wọn ba gbe le e lọwọ. O ṣee ṣe ko jẹ nigba tawọn ti wọn n ba a ṣiṣẹ ri i pe aṣiri ọrọ naa ti n tu sita ju bo ṣe yẹ lọ, ni wọn ko ṣe jẹ ko sọrọ nita mọ. Bẹẹ ni ki i jade! Eyi si ti wa bẹẹ tipẹ.

Ohun to jẹ ki inu awọn araalu dun ree, iyẹn lọsẹ to kọja lọhun-un, nigba ti awọn aṣofin ilẹ wa pe Buhari pe ko maa bọ, ko waa ṣalaye awọn ohun kan to n lọ fawọn nipa eto aabo orilẹ-ede yii, ati idi ti awọn Boko Haram ṣe n paayan kaakiri. Ọjọ kin-in-ni, oṣu kejila yii, ni wọn ṣe apero nile-igbimọ bẹẹ, ti gbogbo awọn aṣofin si fọwọ si i pe ki wọn pe aarẹ ko waa ba awọn sọrọ, ko si ti ọdọ awọn ba gbogbo ọmọ Naijiria sọrọ, nigba to jẹ ojutaye ni yoo ti sọrọ, gbogbo awọn ọmọ Naijiria yoo si gbọ ohun to ba sọ. Wọn ni bo ba waa sọrọ bayii, to sọ awọn ohun ti oun gẹgẹ bIi Aarẹ, ati ileeṣẹ rẹ n ṣe si ọrọ yii, ọkan awọn araalu yoo balẹ, wọn yoo si mọ pe Aarẹ wọn ko kawọ gbera, o n ba iṣẹ lọ. Ati pe awọn eeyan yoo tun ni anfaani lati mọ pe loootọ ni aarẹ wọn ko ku, pe alaafia ni Buhari wa, ko si si ohun to ṣe e lọpọlọ.

 

 

Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja yii, ni wọn fi ipade naa si, ti gbogbo ọmọ Naijiria yoo ri Aarẹ wọn, ti wọn yoo si jọ fikun lukun nile-igbimọ, ki wọn le mọ ohun ti wọn yoo ṣe si ọrọ Boko Haram to gba ọna oko ati ọna odo lọwọ awọn araalu gbogbo, paapaa l’Oke-Ọya. Ṣebi ohun to mu ọrọ yii jade gan-an ni pipa ti awọn Boko Haram yii lọọ dumbu awọn agbẹ onirẹsi mẹtalelogoji mọ inu oko wọn lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kọkanla, to kọja yii, ti ọrọ naa si ka gbogbo agbaye lara. Bẹẹ, awọn ṣọja ti n sọ pe awọn ti yanju ọrọ Boko Haram tẹlẹ, ti wọn ni ko si awọn afẹmiṣofo naa nibi kankan ni Naijiria mọ. Ohun to jẹ ki wọn ranṣẹ si Buhari niyi, pe ki lo tun ṣẹlẹ, nitori awọn eeyan rẹ ti sọ pe ko si wahala Boko Haram yii mọ, bẹẹ awọn ti wọn paayan yii ti fẹnu ara wọ sọ pe awọn Boko Haram ni. Yatọ si eyi ẹwẹ, eto aabo gbogbo ti bajẹ nilẹ Hausa, ẹmi awọn eeyan ko de rara.

Ipade eleyii yoo tilẹ yatọ, nitori awọn aṣofin naa fẹ ki Buhari waa fi ẹnu ara rẹ sọrọ ni. Iyẹn ni pe ko si ẹni kan ti yoo kọ ọrọ ti yoo ka fun un, wọn ni awọn ko fẹ ko jẹ yoo maa ka ̀ọrọ ti awọn kan ti kọ silẹ fun un ni, wọn fẹ ko wa, ki awọn jọ fikun-lukun, ki awọn si jọ fọrọ jomitoro ọrọ ni, ki awọn maa beere ọrọ lorukọ awọn ọmọ Naijiria, ki oun naa si maa ṣalaye awọn ohun to ba mọ fun wọn.  Ko si ẹni to gbọ ọrọ naa ninu awọn ọmọ Naijiria ti inu wọn ko dun, wọn si bẹrẹ si i kan saara si Fẹmi Gbajabiamila ati awọn aṣaaju ile-igbimọ aṣoju-ṣofin ti wọn gbe aba yii kalẹ, bẹẹ ni wọn n dupẹ lọwọ Mamman Lawan, ẹni ti i ṣe Aarẹ ile-igbimọ aṣofin agba, bi oun ati awọn eeyan rẹ ṣe gba kinni naa wọle, nitori ile igbimọ mejeeji ni Buhari yoo ba sọrọ papọ, yoo fi oko kan pa ẹyẹ meji ni.

Ṣugbọn ohun ti awọn ọmọ Naijiria ko mọ ni pe bi awọn ti n gbimọ bayii lati da aṣọ aṣiri bo Buhari loju araalu, pe ko waa sọ ti ẹnu rẹ ki wọn le maa ṣe apọnle fun un, awọn kan wa ni kọrọ, paapaa ninu Aso Rock, ti inu wọn o dun si kinni naa rara, wọn ko fẹ ki Buhari jade si gbangba ko waa sọrọ, wọn ni ko daa, nnkan yoo bajẹ bi baba naa ba le jade. Bayii ni wọn bẹrẹ si i sare a-sa-fori-sọganna, ti wọn n lọ, ti wọn n bọ, lati ri i pe ipade naa ko ni i ṣee ṣe, Buhari ko ni i yọju si wọn. Ohun to tilẹ ba wọn lẹru ju ni pe lẹyin ti awọn aṣofin ti kọwe si Buhari lori ipinnu wọn, oun naa ti da esi pada pe lagbara Ọlọrun, oun yoo yọju si wọn bi wọn ti wi nile-igbimọ naa lọjọ kẹwaa, oṣu kejila yii, iyẹn ọjọ ti wọn ni awọn yoo ri oun. Boya oun lo kọwe naa o, boya awọn eeyan rẹ ti wọn maa n sọrọ lorukọ rẹ lai gba aṣẹ lọwọ rẹ lo kọ ọ o, iyẹn ni ALAROYE ko ti i le sọ titi di asiko yii. Ṣugbọn Aarẹ ti fesi pada, o loun yoo yọju si awọn to n pe oun.

Bi ọjọ ti Buhari yoo yọju si awọn aṣofin yii ti ku gẹngẹ, iyẹn ni Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ to ku ọla ti Aarẹ yoo ri awọn aṣofin, Abubakar Malami ti i ṣe minisita eto idajọ nilẹ wa, gbe iwe kan sita, ohun to si wa ninu iwe naa ni pe ile-igbimọ aṣofin ko lẹtọọ labẹ ofin lati ranṣẹ si Buhari pe ko waa sọ ohunkohun nipa bi ijọba rẹ ṣe n gbogun ti Boko Haram. O ni ofin ko faaye iru nnkan bẹẹ gba awọn aṣofin rara. Malami ni arun oju lọrọ to wa nilẹ yii o, ki i ṣe arun inu rara, pe ko si ọmọ Naijiria ti yoo ni oun ko ri gudugudu meje ati yaayaa mẹfa ti Buhari ti ṣe lọrọ Boko Haram lati igba to ti gbajọba. O ni awọn Boko Haram ti wọn ti gbilẹ rẹpẹtẹ ki baba yii too gbajọba, gbogbo wọn lo ti le danu, to si ti gba ọpọlọpọ ilẹ Hausa ti awọn afẹmiṣofo naa ti n paṣẹ tẹlẹ kuro lọwọ wọn. Nitori bẹẹ, ko si ẹni ti yoo sọ pe oun ko ri ohun ti Buhari n ṣe lori ọrọ yii.

Malami ni oun tilẹ tun fẹẹ sọ kinni kan fun gbogbo ọmọ Naijiria, iyẹn naa ni pe ọrọ ogun jija, ọro eto aabo, ki i ṣe ohun ti wọn n sọ mi gbangba bẹẹ, nitori o tun le da wahala mi-in silẹ si i. O ni kọrọ, nibi ti ko ti si awọn oniroyin tabi awọn agbọfinrin ti i ro ẹjọ ẹlẹjọ kiri, ni iru ọrọ bẹẹ ti ṣee sọ, ki i ṣe loju ọgbagade, nibi ti kaluku yoo ti maa sọrọ wọṣọwọṣọ rara. O ni Buhari nikan lo le ro o ninu ara rẹ pe oun fẹẹ ṣalaye ohun to n lọ fawọn aṣofin o, tabi pe oun fẹ ki wọn mọ bi nnkan ṣe n lọ si. Wọn ni bo ba jẹ oun lo sọ pe oun fẹẹ sọrọ bẹẹ, a jẹ pe lati ọkan rẹ lo ti wa niyẹn, nitori oun naa lo lagbara lati ṣe bẹẹ, ki i waa ṣe ki awọn aṣofin fẹyin ara wọn ti sibi kan, ki wọn ni awọn yoo pe Aarẹ ko waa sọrọ niwaju gbogbo ilu, nitori ohun to n lọ ninu igbo awọn afẹmiṣofo. Malami ni ohun ti ko sunwọn gbaa ni.

Ohun ti Malami ko ranti sọ fawọn eeyan ni pe iru ọrọ yii naa ti waye ri o. O ti waye ni ọdun 2012, nigba ti Goodluck Jonathan n ṣejọba. Ninu oṣu kẹfa, ọdun naa ni, nigba naa lawọn aṣofin ranṣẹ si Jonathan pe ko waa ṣalaye ibi to ba ọrọ awọn Boko Haram igba naa de, bẹẹ ni tootọ, nnkan ko le nigba naa to ti asiko yii rara, nitori ko si ibi ti awọn Boko Haram ti pa ogoji eeyan lẹẹkan. Sibẹ, awọn aṣofin igba naa ni eni tere, eji tere, awọn eeyan ti awọn Boko Haram yii n pa, ati ihalẹ ti wọn n ṣe faraalu, to ohun ti awọn agbaagba ilu gbọdọ yẹ wo, nigba ti o si jẹ Jonathan ni olori ijọba, ko yaa maa bọ lọdọ awọn, ko waa fẹnu ara rẹ sọ ohun to n lọ. N lawọn kan ninu ẹgbẹ PDP igba naa ba bẹrẹ si i gbemu, wọn ni aarẹ laarẹ yoo maa jẹ, arifin ni ki awọn aṣofin pe Aarẹ. Ni awọn ọmọ ẹgbẹ ACN to pada waa di APC igba naa ba binu rangbọndan.

Lara awọn ti wọn binu gan-an nigba naa, awọn meji wa ninu ijọba Buhari yii ti wọn jẹ ọlọwọ ọtun rẹ, idi ti wọn ko si fi sọ iru ọrọ ti wọn sọ nigba naa bayii ni ko ti i ye awọn eeyan. Awọn mejeeji naa ni Babatunde Raji Faṣọla ti i ṣe gomina Eko nigba kan, to si jẹ minisita nla ninu ijọba yii, ati Festus Keyamo, ajafẹtọọ ọmọniyan, toun naa tun jẹ minisita fun Buhari. Awọn mejeeji ni wọn binu nigba naa, ti wọn n tu bii ejo, ti gbogbo awọn oniweeroyin si gbe ibinu wọn si Jonathan jade. Faṣọla ni, “kin ni wọn n sọ ti ko dun paapaa! Bi ile-igbimọ aṣofin ba pe ẹnikẹni, dandan ni ki tọhun lọ. Awọn ile-igbimọ yii laṣẹ ati agbara lati pe Aarẹ nigba yoowu ti wọn ba fẹ, nitori o gbọdọ lọ lati ṣe alaye ohun ti wọn ba fẹẹ mọ fun wọn. Emi ko ri idi kankan ti wọn yoo fi maa pọn jẹbẹ lakiisa, bi ile-igbimọ ba pe Aarẹ, ko tete lọọ yọju si wọn!”

Bi ọrọ ba da bayii, ti Faṣọla ba sọrọ, afi ki gbogbo ẹni ti ko ba mọ nipa oifn ṣe gaaya, nitori ọga awọn amofin ti wọn n pe ni SAN, agbẹjọro-agba nilẹ wa, ni. Ọrọ ti oun tilẹ sọ ko tun nikimi to eyi ti Keyamo sọ, nitori niṣe ni Keyamo tọwọ bọ iwe ofin.  O ni ohun ti ẹsẹ ofin kọkandinlaaadọrun-un (Section 89 (1) (C) ti ọdun 1999 sọ ni pe “Ile-igbimọ laṣẹ lati pe ẹnikẹni ni Naijiria pe ki wọn waa ṣalaye ọrọ niwaju awọn, tabi ki wọn kọ awọn iwe yoowu ti wọn ba beere wa!” Keyamo ni pẹlu eyi, ofin ko yọ ẹnikẹni silẹ, koda ki tohun jẹ aarẹ. O ni loootọ iru ipe bẹẹ gbọdọ jẹ eyi to ba ofin mu o, ṣugbọn bi wọn ti pe Aarẹ Jonathan yii ba ofin mu pupọ, nitori nipa alaafia aabo ilu ati ijọba rere ni wọn tori ẹ ni ko waa yọju sawọn, pe nitori bẹẹ, ko si ohun to yẹ ko maa da Jonathan duro, o gbọdọ yọju si awọn aṣofin yii dandan ni.

Bi ọrọ naa ti gbona lọdun naa lọhun-un ree, ohun ti awọn eeyan si n beere ni pe nibo ni Faṣọla ati Keyamo wa bayii o, ki lo waa de ti wọn ko ba Buhari sọ iru ọrọ ti wọn ba Jonathan sọ ni 2012 yii. Ohun ti awọn kan ko si ṣe fẹran ọrọ ti Malami naa n sọ ree, wọn ni gẹgẹ bii olori eto idajọ ati agbalagba lọọya ti oun naa jẹ, o yẹ ko mọ itumọ ofin bayii, ko si yẹ ko jẹ oun ni awọn kan yoo lo lati gbegi dina fawọn araalu lati foju ri Aarẹ wọn, tabi lati gbọrọ lẹnu rẹ niwaju awọn aṣofin. Ohun ti Malami paapaa ko sọ fawọn araalu ko too gbe iwe jade ni pe awọn kan ni Aso Rock ti lo awọn gomina ipinlẹ gbogbo to jẹ ti APC, wọn ti ni ki wọn ṣe pade, ki wọn si sọ fawọn aṣofin ki wọn jawọ ninu ohun ti wọn fẹẹ ṣe. Ni alẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹjọ, oṣu yii, lawọn ṣepade naa, wọn si ṣe ipade ọhun wọ ilẹ mọ lọjọ keji ni.

Alaga Ẹgbẹ awọn gomina APC, ẹni ti i tun ṣe gomina ipinlẹ Kẹbbi, Atiku Bagudu, lo dari ipade naa. Ipade ọhun jẹ laarin awọn gomina APC, ati awọn aṣaaju awọn ọmọ ile-igbimọ aṣofin ti wọn jẹ APC. Nibi ipade yii, Ahmad Lawan ti i ṣe olori ile-igbimọ aṣofin agba, ati Fẹmi Gbajabiamila ti i ṣe olori ile-igbimọ aṣoju-ṣofin naa wa nibẹ, ohun ti awọn gomina yii si ṣe pe ipade yii naa ni ki awọn aṣofin jawọ ninu ohun ti wọn fẹẹ ṣe. Njẹ kin ni idi ti wọn yoo fi jawọ. Awọn gomina yii ni bi ẹni to fẹẹ fẹdi ẹgbẹ awọn sita ni bi awọn eeyan naa ba pe Buhari, nitori wọn ni awọn ọmọ ẹgbẹ PDP ti duro wamu lati da yẹyẹ Aarẹ silẹ loju gbogbo araalu patapata. Awọn gomina yii ni awọn ibeere ti awọn aṣofin ọmọ PDP yoo maa beere lọwọ Aarẹ niwaju ile-igbimọ, awọn ibeere ti yoo fi Buhari ṣe yẹyẹ ni, nitori ero ọkan wọn gan-an niyẹn.

Yatọ si eyi, awọn gomina naa ni bi wọn ba ṣe bayii pe Buhari, awọn aṣofin ni ipinlẹ awọn gbogbo ko ni i jẹ ki awọn naa gbadun mọ, nitori ni gbogbo igba ni wọn yoo maa ranṣẹ pe awọn pe ki awọn waa ṣalaye ohun kan tabi omi-in, ti wọn ko si ni i jẹ ki awọn ri aaye ṣe iṣẹ awọn bii gomina mọ rara. Awọn aṣofin to wa nibẹ ko gba, wọn ni ko si ohun to jọ gbogbo ohun ti awọn gomina naa n sọ. Wọn ni lakọọkọ, awọn aṣofin APC pọ ju ti PDP lọ, ko si si bi wọn yoo ṣe gbori lọwọ awọn. Lọna keji, wọn ni ti ọrọ ba ti da bayii, ọkan naa lawọn aṣofin, iṣẹ kan naa ni awọn si jọ maa n ṣe. Wọn ni ṣebi ni aipẹ yii ni Buhari gbe iwe eto-inawo rẹ fun ọdun to n bọ wa sile-igbimọ, ki lo waa de ti wọn ko fi i ṣe yẹyẹ, tabi ki awọn PDP to wa nibẹ maa bu u. Wọn ni eleyii ko ri bẹẹ rara, nitori ẹ, ki awọn gomina kan wa nnkan mi-in sọ.

Ṣugbọn ko si ohun ti awọn gomina naa tun le sọ ju ki wọn bẹrẹ si i jagbe mọ awọn aṣofin naa pe ohun ti ileeṣẹ Aarẹ fẹ niyẹn, ẹni to ba si ti lodi si ti ileeṣẹ Aarẹ, iyẹn awọn ara Aso Rock, ko si bi oluwaarẹ yoo ṣe ri tikẹẹti ẹgbẹ APC gba lati tun le pada wa si ile-igbimọ aṣofin ni ọdun 2023. Bayii ni awọn aṣofin ti wọn bẹru ohun to le ṣẹlẹ si wọn loootọ sọrẹnda, wọn ko si le wi kinni kan mọ, nnkan ti wọn fohun si ni pe bi Aarẹ ko ba wa, awọn ko ni i fi dandan le e pe ko wa. Koda, ALAROYE gbọ pe Fẹmi Gbajabiamila ko le sọrọ nipade naa, o fọwọlẹran titi ti wọn fi fori ẹ ti sibi ti wọn fi i ti si yii ni, ohun to si n sọ ni pe oun fẹẹ fi aaye silẹ fun awọn ẹlẹgbẹ oun lati ile-igbimọ ki wọn sọ tinu wọn, ibi ti wọn ba si fori ọrọ ti si ni oun gẹgẹ bii olori yoo maa tẹle wọn lọ. Bo tilẹ jẹ pe ki i ṣe gbogbo awọn aṣọfin lo wa nibẹ, ohun ti wọn mọ ni pe awọn ara Aso Rock, nileeṣẹ Aarẹ, ni ko fẹ ki Buhari yọju.

Ohun ti wọn ko ṣe fẹ ki Buhari yọju ni pe wọn ti sọ ọ laarin ara wọn ni pe ti Buhari ba de gbangba, ko si bo ṣe le dahun awọn ibeere ti wọn ba n bi i, nitori aiyaara rẹ to ti wọ ọ lara. ALAROYE gbọ pe lati igba ti Buhari ti ṣe aisan ti wọn tori ẹ gbe e lọ si ilu oyinbo, to si pẹ nibẹ titi, lati igba naa ni laakaye, ati ọpọlọ rẹ ko ti fi bẹẹ gbe ohun to n lọ mọ. Wọn ni ki i ranti ọrọ, bẹẹ ni i maa tete gbagbe nnkan. Yatọ si eyi, ki i le i ro arojinlẹ lori ọrọ, bi ọrọ kan ba si ta koko, ohun yoowu to ba bọ si i lẹnu nigba naa ni yoo sọ. Nidii eyi, bi Buhari ba jade si gbangba, ti awọn aṣofin ba da ibeere bo o, awo yoo ya, aṣiri yoo tu, pe Buhari to n ṣejọba Naijiria yii ko gbadun rara. Eleyii yoo fi han gbogbo ọmọ Naijiria pe ọpọ ohun to n ṣẹlẹ ni ile ijọba ni Buhari ko mọ, awọn kan ni wọn si jokoo sibi kan ti wọn ja ọpa aṣẹ gba mọ ọn lọwọ, ti wọn n fi orukọ rẹ ṣe ohun to wu wọn, ti wọn si n tan awọn ọmọ Naijiria jẹ.

Awọn aṣofin kan ti n leri pe awọn ko gba, koda Olori awọn aṣoju-ṣofin, Gbajabiamila, tun tẹnu mọ ọn pe Buhari funra ẹ lo jẹjẹẹ fawọn pe oun n bọ, ko si ti i fẹnu ara rẹ sọ pe oun ko ni i wa mọ, oun si mọ pe ẹni kan ti i maa a mu adehun ṣẹ ni, nitori bẹẹ ni awọn aṣofin si ṣe n reti rẹ, awọn fẹ ko waa ba awọn sọrọ, nitori olori awọn ni. Boya Buhari yoo waa tun ero rẹ pa ni o, pe yoo fi agidi wa siwaju awọn ọmọ ile-igbimọ yii, boya ko si ni i da wọn lohun bi awọn eeyan rẹ ti ṣe wi, o digba naa na, ka too fọmọọba fọṣun.

Leave a Reply