Faith Adebọla, Eko
Ogbontarigi akọwe-kọ-wura nni, Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka, ti sọ pe ọrọ ẹsin to gbalẹ kan lorileede Naijiria jẹ akọkọ lara iṣoro ti ko jẹ kawọn eeyan le ronu bo ṣe tọ ati bo ṣe yẹ, eyi lo si n fa iwa aibojumu ti wọn maa n hu lọpọ igba.
O ni ọpọ awawi, ojuṣaaju ati igbọjẹgẹ lo maa n ṣẹlẹ tọrọ ba ti dọrọ ẹsin, niṣe lawọn eeyan maa n fi ọrọ ẹsin rọpo laakaye wọn, awọn mi-in si maa n ki aṣeju bọ ọ debi ti wọn aa fi sọ ara wọn di agbawere-mẹsin.
Ṣoyinka sọrọ yii lọjọ Abamẹta, Satide yii, lasiko to n jiroro awọn iṣoro to n koju ilẹ aAdulawọ pẹlu ọjọgbọn nipa iwe kikọ nilẹ Afrika, Dokita Louisa Egbunike, to sabẹwo si i l’Ekoo.
Ṣoyinka ni: “Ọrọ ẹsin ti di iṣoro akọkọ fawọn ọmọ Naijiria. O daa lati ni igbagbọ ati ireti, ṣugbọn bi ireti naa ba jẹ tori keeyan le maa rẹ ọmọlakeji jẹ ni, ireti radarada niyẹn. Bi ẹsin ba jẹ nnkan tawọn eeyan fi n ṣe awawi lati rufin, lati huwa aidaa, o yẹ ka gbogun ti iru ẹsin bẹẹ ni.
“Fun apẹẹrẹ, tori pe awọn kan fẹẹ ṣajọdun ẹsin, wọn aa di ọna marosẹ Eko to lọ sawọn ipinlẹ mi-in pa bamu, wọn o si ri nnkan to buru ninu ohun ti wọn n ṣe, tori wọn ti ko aṣọ ojiṣẹ Ọlọrun sọrun. Bẹẹ iwọnba eeyan ni wọn jẹ lẹgbẹ gbogbo araalu to ku o, ṣugbọn wọn aa ki aṣeju bọ ọ, tori wọn lawọn n ṣe ẹsin.
“O le jẹ aṣofin kan, to di gomina nigba to ya, o le maa huwa ibalopọ ti ko yẹ pẹlu ọmọde, o le maa fawọn eeyan ṣe fayawọ, ko maa ṣayẹyẹ igbeyawo pẹlu awọn ọmọde, awọn iwa ti ko ba ofin ilẹ wa mu, ṣugbọn o le ni ẹsin oun lo faaye gba iru nnkan bẹẹ, bẹẹ niṣe lo yẹ kijọba wọ oun ati ẹsin ẹ ọhun dewaju adajọ, ki wọn si foju ọbayejẹ wo wọn.
“Wọn n kọle ẹbiti to n wo pa awọn eeyan lorukọ ẹsin, to jẹ pe ọpọ awọn to ku ki i ṣọmọ Naijiria, orileede South Africa ni wọn ti wa, ṣugbọn kaka ki ẹlẹbi gba ẹbi ẹ, o ni ẹmi airi kan lo wa nidii iṣẹlẹ ọhun, bẹẹ o mọ pe awọn ti kọ ile yẹn ga ju nnkan to yẹ lọ o.
“Ko sohun to buru ninu keeyan ṣe ẹsin labẹ orule ẹ, o le ko awọn ti wọn ba nifẹẹ si ẹsin jọ, ki wọn maa ṣe ajọdun tabi ayẹyẹ wọn, ṣugbọn to ba ti di pe eeyan n fi ẹsin ẹ di awọn mi-in lọwọ, to si fi n tẹ ẹtọ wọn mọlẹ, iwa aburu gbaa ni. Awọn kan ti gbe ẹsin leri debi ti wọn n dana sun ileejọsin awọn ẹlẹsin mi-in, ti wọn n forukọ ẹsin paayan, ti wọn n ṣeṣekuṣe kaakiri, tori wọn pe ara wọn l’ojiṣẹ Ọlọrun, iwa ọdaran gidi ni wọn n hu, ibi ti nnkan si bajẹ de ni Naijiria wa yii niyẹn.”
Bẹẹ ni Wọle Ṣoyinka wi.