Ọrọ Fulani to n halẹ mọ wọn n’Ibarapa: Ki i ṣe pe a lojo o, oju ijọba la n wo – Ọba Ayetẹ

Faith Adebọla

Ọkan lara olori awọn Fulani ti wọn fẹsun kan pe o n dun mọhuru-mọhuru mọ awọn agbẹ, pe o n ko awọn ọmoogun Fulani rẹpẹtẹ jọ , to si n fi maaluu jẹ ire-oko wọn lagbegbe Ibarapa ni Iskilu Wakili, ṣugbọn Aṣawo tilu Ayetẹ, Ọba Emmanuel Okeniyi ti ni kawọn araalu fọkan balẹ, awọn maa ri i pe olori awọn Fulani naa kuro lagbegbe ọhun, awọn ṣi n ro’wọ fun ijọba ni.

Nigba to n ba ALAROYE sọrọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, ni Ọba Okeniyi sọrọ ọhun, o ni loootọ ni Fulani yii ṣi n dun mọhurumọhuru mọ awọn agbẹ ataraalu, tọkan ẹnikẹni o balẹ, ṣugbọn o daju pe ago awọn lo maa de adiẹ rẹ kẹyin.

Kabiesi ni nigba ti gomina ti wa, to ti ṣeleri, afi kawọn ṣi duro wo ohun ti ijọba maa ṣe na, awọn si reti pe ki ijọba ma ṣe fi ọrọ aabo to mẹhẹ yii falẹ.

“Ṣe ẹ mọ pe iṣẹ agbẹ ni lajori iṣẹ wa nilẹ yii, eeyan to ba si ṣe idiwọ fun ẹnikan lọna atijẹ atimu ẹ, apaayan lo yẹ ka pe onitọhun, iyẹn lo fi jẹ pe bawọn agbẹ ko ṣe le lọ sẹnu iṣẹ oko wọn yii, ki i ṣe nnkan ti o le wa bẹẹ titi. Ki si i ṣe pe ẹru Wakili atawọn Fulani rẹ n ba wa, ṣugbọn nigba ti ijọba ti da si i, ti gomina Makinde ti waa ba wa sọrọ, afi ka ni suuru na, ko reti ohun ti ijọba yoo ṣe.

Ni ti ibeere awọn ọdọ pe awọn ko fẹẹ ri Fulani kankan ni gbogbo agbegbe Ibarapa, ṣe ẹ mọ pe awọn ni a jọba le lori, awọn ni ilu, awa kan jẹ olori wọn ni, tori naa, ti ilu ba sọ pe ohun kan lawọn fẹ tabi lawọn ko fẹ, afi ki ẹni to n ṣakoso gbọ tiwọn. Gomina naa si ti sọ pe oun maa gbe ẹbẹ wa yẹ wo.

“Amọran mi fun awọn eeyan mi ni pe ki wọn mu suuru diẹ si i, ka reti ohun tijọba maa ṣe. O daju pe ọkunrin naa ko le lagbara ju ijọba ataraalu lọ.

Leave a Reply