Ọrọ ijọba ibilẹ ni Naijiria nilo adura, ojoojumọ lo n buru si i fun wọn- Ọbasanjọ

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

 

Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹfa, ọsu kẹrin, ọdun 2021 yii, Aarẹ fẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ ni Naijiria, (NULGE) Kọmureedi Akeem Ọlatunji Ambali, ṣabẹwo si aarẹ ana, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, lati ṣalaye ohun toju awọn ijọba ibilẹ n ri lasiko yii. Nigba naa ni Ọbasanjọ sọ pe ọrọ ijọba ibilẹ lorilẹ-ede yii nilo adura, nitori ojoojumọ lo n buru si i fun wọn.

Kọmureedi Ambali ṣalaye nile Ọbasanjọ, OOPL l’Abẹokuta, pe ajọ awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ nilo iranlọwọ rẹ bayii, pẹlu bi ile-igbimọ aṣofin agba ṣe kuku fẹẹ fagile ijọba ibilẹ patapata, ti wọn fẹẹ yọ wọn danu ninu ofin orilẹ-ede Naijiria ti wọn ṣe lọdun 1999.

Ambali ṣapejuwe abadofin tawọn aṣofin gbe kalẹ naa gẹgẹ bii igbiyanju lati pa ohun to n jẹ ijọba ibilẹ rẹ raurau ni Naijiria. Nitori eyi, o ni aṣẹ ti wa pe ki gbogbo awọn olori yuniọnu kọọkan ṣabẹwo sọdọ awọn aṣofin ni ẹkun ti wọn ba wa, ki wọn si ri i daju pe wọn duro ti awọn eeyan wọn ti ọrọ yii yoo kan bi aba to lewu naa ba fi le di ofin.

Aarẹ awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ naa fi kun un pe nigba ti wọn ko tiẹ ti i yọwọ awọn kuro ninu awo patapata, awọn ki i rowo gba lasiko, awọn gomina ipinlẹ nijọba apapọ n kowo awọn fun, ti wọn n ṣe awọn bo ṣe wu wọn. Bawo ni yoo ṣe waa ri nigba ti wọn ba kuku fagi le ijọba ibilẹ raurau, aa jẹ pe ko ni i si idagbasoke kankan mọ lẹka ibilẹ niyẹn.

Ki iru eyi ma baa ṣẹlẹ lo ni awọn ṣe waa ba Ọbasanjọ bayii, ki baba naa le da si ọrọ ijọba ibilẹ to bẹrẹ lọdun 1976, lasiko ti Ọbasanjọ n ṣẹjọba ṣọja lọwọ.

Nigba to n fesi, Oloye Ọbasanjọ sọ pe ki i ṣe ohun ti oun foju sun nigba ti ijọba ibilẹ bẹrẹ lo n ṣẹlẹ lasiko yii. O ni ti asiko yii buru jai to jẹ ohun to n ṣẹlẹ nilo adura ati idasi Ọlọrun latoke wa. Ọbasanjọ sọ pe niṣe ni nnkan n buru si i lẹka ijọba ibilẹ gbogbo.

‘‘Awọn ṣọja lo kọkọ ba nnkan jẹ, nigba ti wọn fẹẹ ni kansu ni gbogbo ibi ti wọn ba wa, wọn waa ṣafikun ẹ lati ọọdunrun (300), wọn sọ ọ di ẹẹdẹgbẹrin ati mẹrindinlọgọrin(774) Ṣugbọn awọn oloṣelu lo tubọ ba a jẹ pẹlu ijẹkujẹ.

‘’O yẹ kijọba ibilẹ le pese awọn nnkan amayedẹrun fawọn eeyan agbegbe wọn, ṣugbọn njẹ iru ẹ wa mọ bayii’’

Bẹẹ ni Ọbasanjọ beere ibeere to pesi jẹ naa, to ni ko sohun to kọja adura, kawọn NULGE fadura kun ohun to wa nilẹ yii ni.

Leave a Reply