Ẹ wo o, ki ire Ọlọrun ma jinna si gbogbo wa. Gbogbo ohun ti a n wa yii, gbogbo ohun ti a n le kiri laye yii, ko to Ọlọrun i ṣe laarin iṣẹju kan. Yoo si ṣe e, yoo si yanju ẹ, yoo si maa ya ọlọrọ funra ẹ lẹnu. Ọlọrun Ọba nikan lo le ṣe iru ẹ, ko si ẹda aye ti i ṣe iru ẹ fun ni. Bi mo ba n sọ iru ọrọ yii, afi kẹ ẹ gba mi gbọ, nitori ohun to ṣẹlẹ si mi ni mo n sọ yii, loju wa nibi yii naa si ni, lori bi nnkan ṣe le to yii naa si ni. Bi ki i ba si i ṣe pe o ṣẹlẹ si emi naa, bo ba jẹ ẹnikan lo sọ ọ, mo maa maa wo o ni, nitori o ṣoroo gbagbọ gan-an ni.
Nigba ti mo de ṣọọbu, Sinkafi ko ti i de, ṣugbọn ọkan Safu ko balẹ, o si han loju ẹ pe inu ẹ ko dun. Mo kọkọ ro pe nnkan mi-in lo n ṣe e ni, afi nigba ti mo beere, ti mo ni ki lo de, ki lo n ṣe e. Lo ba ni ọrọ irẹsi yii naa ni, nigba ti a ko ti i ri awọn ti wọn yoo ko irẹsi fun wa, bawo la ṣe waa fẹẹ ṣe.
Ni mo ba rẹrin-in musẹ, mo ni ṣebi oun lo ti sọ fun mi tẹlẹ pe Ọlọrun maa ṣe gbogbo ẹ ni aṣeyọri, o ni bẹẹ ni. Mo ni, “Ẹn ẹn, Ọlọrun ti ṣe e!” Ni mo ba ṣalaye fun un bo ṣe jẹ Alaaji Ṣinkafi to wa lọ si Tinkan, l’Apapa, ti ko ri funra ẹ lo pe mi o.
Mo ṣalaye fun un pe bo ṣe kuro lọdọ mi yẹn, bẹẹ ni ipe Alaaji yẹn wọle. O ni ki lo waa sọ fun mi. Mo ni o n wa mi ni, koda o n ba mi ja ni. O ni ki lo de to n ba mi ja. Mo ni o n ba mi ja pe oun ti ni irẹsi lati ọjọ yii, irẹsi awọn ti wa lori omi tipẹ, emi o ba oun da si i, n o fẹẹ gba ọja tabi ki n ba oun wa awọn to maa waa ko o, pe mo waa fi oun silẹ lati ọjọ yii wa. Niṣe ni Safu pariwo, ‘Alau akbar, Alau akbar!’ Lo ba n jẹnu wuyẹwuyẹ lo n ke awọn kewu kan. Emi naa mi o mọgba ti mo bẹrẹ si i rawọ si Ọlọrun Ọba. Mo n dupẹ naa ni.
Kia ni Safu ti bẹrẹ si i palẹmọ, to n tun ibi to ti tun ṣe tẹlẹ ṣe. Gbogbo eyi ti a n ṣe yii, a ko ti i pari ẹ nigba ti mọto kan duro sita, pikọọbu tuntun ni, kiakia ni Alaaji Ṣinkafi bọ silẹ niwaju ẹ, ni mo ba n sọ fun Safu pe ẹni ti a n wi niyẹn o.
Safu ni ọkunrin ọhun ṣe waa dudu bii eedu bayii, to tun kuru, pẹlu ikun kẹrẹbẹtẹ, ni mo ba sọ fun un pe ko rọra sọrọ o, Ṣinkafi gbọ Yoruba taataataa o. Kia lo ti yaa yi oju ẹ si tẹrin, to fi ọyaya pade Alaaji onirẹsi yii. Nigba tiyẹn wọle naa, ija nla lo tun gbe ko mi. ‘Alaaja, ẹ ko ṣe daadaa fun mi rara! Baa ṣau walai!”
Mo ṣalaye fun un pe ki i ṣe bẹẹ, mo ni ọja ni ko ta, ati ọrọ ogun onikorona yii. O ni o ye oun, ṣugbọn awọn ti fẹẹ jẹ gbese bayii, ki n mọ bi a ṣe maa waa ko o ni. Ni mo ba pe Safu si i, mo ni eelo lawọn eeyan n ṣe irẹsi bayii lọja, Safu ni ẹgbẹrun mẹwaa naira ma ni, tipatipa lawọn fi n ti ẹgbẹrun mọkanla ti i mọ wọn lọrun. Mo fẹẹ pariwo pe ‘Safuuuuuu, aye ẹ ree!’ Abi bawo leeyan ṣe n moju owo to bayii. Irẹsi to ti pe ni bii ẹgbẹrun lọna ọgbọn fun awọn ti wọn fẹẹ ra a, to wa n sọ pe ẹgbẹrun mẹwaa si mọkanla fawọn toun fẹẹ ra a lọwọ ẹ.
Ṣugbọn iyanu to wa nibẹ ni pe Alaaji Ṣinkafi ni ọrọ emi ati oun ko ni wahala ninu. Alaaji ni ko gba iye ti Safu pe e yẹn, koda ko jẹ olokuta ti wọn ko fẹ rara to jẹ kiki panti, ṣugbọn iye to ba dara ni ki n ra a lọwọ awọn, ki n ṣaa waa maa ko o kuro nibẹ. Bi mo ṣe ni ko maa lọ niyẹn. Bo ba ti di lọla, mo maa ran tirela si i. Inu ẹ ti dun ju, a lo tun fun Safu lowo, faifu taosan. O ni ki n ṣaa maa kọ iye apo irẹsi ti a ba ko silẹ, oun maa waa gbowo to ba ya. Bi mo ṣe pe awọn araabi yii ree, iyẹn awọn onirẹsi, mo ni ki wọn ṣeto tirela ranṣẹ, pe ọja wọn ti wa nilẹ. Wọn ni tireeni lawọn fẹẹ fi ko o, ki awa ṣaa ti ba awọn ko o de Ido, o pari niyẹn.
Mo ni ko si owo mọto ninu owo ta a gba o, wọn ni awọn mọ. Pe awọn maa ṣẹ owo mọto mọ owo fun mi, wọn ni awọn ti beere, wọn ni tirela kan to maa n loodu simẹnti kun lati Apapa de Ido, pe ẹgbẹrun lọna ọgọfa ni wọn n gba. Mo fẹẹ pariwo, ṣugbọn nigba to jẹ awọn funra wọn ni wọn sọ bẹẹ, Ọlọrun lo mọ awọn ti wọn jọ n ṣe to sọ iyẹn fun wọn. Alaaji Ṣinkafi ni mo pe pe ko wa awọn tirela ti a n lo, ko si ti de Apapa to ti maa n pade wa, ko ti ṣeto bii ogun tirela ti wọn le ko irẹsi de Ido lẹẹkan. Ti mo ba sọ fun yin pe ohun ti a fi gbogbo ọsẹ to lọ lọhun-un yẹn ṣe niyẹn nkọ!
Nigba ti awọn ọrẹ mi to n ra irẹsi gbọ pe tirela ogun lo loodu lẹẹkan, ti wọn ko irẹsi wa si Ido, niṣe ni wọn tun fi owo mi-in ranṣẹ sinu akaunti mi. Emi o kuku tiẹ mọ, nitori n ko ri alaati, wọn ni nẹtiwọọku ko daa, afi nigba ti wọn pe mi ti mo lọọ wo o, mo ri i pe wọn ti fi owo irẹsi mi-in ranṣẹ, wọn san balansi eyi ti wọn ra tẹlẹ, wọn si fi ọpọlọpọ owo ti wọn ni owo tirela si i. Owo ti wọn n san lori tirela yii gan-an tooyan ṣe nnkan rere, ka ma ti i sọ owo ti irẹsi funra ẹ, bẹẹ ni wọn tun n sọ pe awọn tun maa fẹ iye apo irẹsi ti awọn ra yẹn si i. Owo naa pọ ju.
Ohun to jẹ ki n rẹrin-in de ọfiisi lọọya mi ree, emi ati Sẹki ati Safu, aago mẹrin irọlẹ ko ti i lu ti awa fi debẹ, nitori asiko ti wọn fi ipade naa si niyẹn. Ṣugbọn bo tilẹ jẹ pe aago naa ko ti i lu, awọn eeyan yẹn ti de sọdọ lọọya, ko sẹni kan to ṣẹku ninu wọn. Nitori ẹ lo ṣe jẹ nigba ti wọn ni mo de bayii, niṣe ni awọn lọọya yẹn sare waa pade mi, ti wọn fi mi si yara ọtọ. Wọn ni ki n jokoo, pe awọn maa lọọ sanwo fun wọn, ki n kọ ṣẹẹki, awọn maa gbawee waa ba mi lẹyin ti a ba ti ṣe gbogbo eto, lẹyin naa la maa too maa rira wa.
Bi awa ṣe fun wọn ni ṣẹẹki ti wọn lọ niyẹn. Ko pẹ ni wọn gbe iwe de, bi wọn ṣe gbe iwe de, a ri i pe wọn ti sain sibẹ, n lemi naa ba sain ati awọn ọmọ mi. Lẹyin iyẹn ni wọn tun lọ, wọn ṣẹṣẹ waa pada waa pe mi nigba to ya. Awọn araabi yẹn ko le gba oju wọn gbọ nigba ti wọn ri i pe emi ni. “Iya Biọla! Iya Biọla! Haa, Iya Biọla!” Bi wọn ṣe n pariwo niyẹn. Emi naa yaa kunlẹ fun wọn, gbogbo wọn ni mo ki tọyaya-tọyaya.
Wọn ya fọto wa, wọn fidio wa, ni gbogbo ẹ ba pari. Lawọn iya yẹn ati awọn baba wọn ba ṣeṣe waa bẹrẹ.
Wọn ni owo ilẹ baba awọn lawọn gba yẹn, ṣugbọn awọn fẹẹ gbowo ti Iya Biọla, nitori eeyan awọn ni, ọmọ awọn ni, ẹgbọn awọn ni, aburo awọn ni. Ni mo ba ni ki Safu ba mi gbe baagi, ni mo ba yọ idi kan ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un, ni mo ba gbe e le wọn lọwọ. Kẹ ẹ waa maa gbọ ariwo, kẹẹ waa maa gbọ adura, adua n rọ bii ojo lẹnu wọn ni. Inu emi naa dun gan-an, nitori mo ri i pe tidunnu-tidunnu ni gbogbo wọn fi tuka nijọ yẹn. Bi mo ṣe ra ilẹ ṣọọbu mi l’Oṣodi ree o.