Ọrọ nipa orileede yii ni mo lọọ ba Kanu sọ l’Abia -Tinubu

Faith Adebọla

 Ṣe ijo to ba ka ni lara la a di’ṣẹ jo, fun bii wakati kan aabọ ni agba-ọjẹ oloṣelu Eko nni, Aṣiwaju Bọla Tinubu, fi tilẹkun mọri ṣepade lọjọ Satide opin ọsẹ yii, pẹlu Gomina ipinlẹ Abia nigba kan, Orji Uzor Kalu, nile ọkunrin naa nipinlẹ Abia. Tinubu ni ọrọ nipa bi Naijiria ṣe maa daa lawọn n sọ.

Nigba to n ba awọn oniroyin ti wọn ti n duro de wọn lati mọ koko ohun tipade naa da le sọrọ, lẹyin toun ati Kalu jade ti wọn si di mọ ara wọn, Tinubu ni ọrọ orileede yii, ipo to wa ati ipenija to n koju wa kọja ọrọ ẹni to n wa ipo oṣelu kan kiri, ati pe ọrọ Naijiria lo jẹ oun logun ju lọ ni toun.

“Mo ṣabẹwo ara-ẹni sibi ni. A sọrọ nipa awọn nnkan to ṣe koko nipa Naijiria, ọrọ aje orileede wa, eto aabo ati awọn nnkan bẹẹ.

Ọrọ to kan orileede yii ṣe pataki ju ọrọ afojusun ipo oṣelu ẹnikẹni lọ. Ọrọ orileede yii lo jẹ mi logun.” Bẹẹ ni Tinubu wi.

Ṣugbọn ṣaaju abẹwo naa lawọn eeyan kan ti n gbe rumọọsi kiri pe afaimọ ko ma jẹ Tinubu ati Kalu ni yoo dupo Aarẹ ati Igbakeji aarẹ papọ lasiko eto idibo gbogbogboo to n bọ lọdun 2023.

Lọwọlọwọ, Orji Uzor Kalu ni Sẹnetọ to n ṣoju ẹkun idibo apapọ Ariwa Abia nileegbimọ aṣofin l’Abuja.

Leave a Reply