Monisọla Saka
Kantankantan lo n jade lẹnu ọkunrin afurasi ẹni ogoji ọdun (40) kan, Anietie Tim, to fipa ba ọmọbinrin ọmọ ọdun mẹrinla kan lajọṣepọ niluu Onitsha, ipinlẹ Anambra, pẹlu bo ṣe di ẹbi ọrọ iwa ibajẹ to hu ọhun ru ọmọdebinrin naa.
Awijare rẹ ni pe ọmọdebinrin naa lo da gbogbo nnkan to ṣẹlẹ silẹ, nitori eeyan ẹlẹran ara loun, oun ko si ribi kọ gbogbo ọwọ to n gbe wa, ati gbogbo bo ṣe n fara ṣe si oun si loun ṣe ṣe ‘kinni’ fun un.
Ileeṣẹ to n ri sọrọ awọn obinrin nipinlẹ naa ni wọn lọọ fi panpẹ ofin gbe ọkunrin yii. Ninu ọrọ rẹ, Arabinrin Ify Obinabo, ti i ṣe kọmiṣanna fọrọ obinrin ati igbaye-gbadun awọn ọmọde nipinlẹ naa, sọ pe o pẹ tawọn ti n wa afurasi naa, ṣugbọn to n yọ bọrọ mọ awọn lọwọ.
Ninu atẹjade to fi sita l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii, lo ti ṣalaye pe lati ọdun 2022 ni afurasi ọhun ti ṣe aṣemaṣe ti wọn fẹsun rẹ kan an yii, latigba naa lo si ti n sa kiri mọ awọn to fẹẹ mu un lọwọ, paapaa ju lọ pẹlu iranlọwọ awọn ologun ti wọn jọ n gbe ninu baraaki kan naa.
O ni, “Afurasi yii, Anietie Tim, to wa lati ilu Eninan, nipinlẹ Akwa-Ibom, ṣalaye lojuna ati le wẹ ara ẹ mọ pe oun ko mọ pe ọmọ kekere lọmọ ti oun fipa ba lo pọ, ati pe ọmọ yẹn lo ti oun si i, nigba to si ti jẹ pe eeyan ẹlẹran ara ti ẹjẹ n ṣan lara ẹ loun, oun ko ri i ka sara, nitori bẹẹ loun fi ṣe e”.
Ọgbẹni Tim tun ṣalaye siwaju si i pe ki iṣẹlẹ naa too waye loun ti n ba ọmọ ọdun mẹrinla naa dọrẹẹ, ati pe niṣe ni wọn maa n febi pa a nile to n gbe, eyi ni oun pẹlu rẹ fi di ọrẹ, ko too di pe ọrọ ibalopọ wọn aarin ajọṣe naa.
Ṣugbọn kọmiṣanna awọn obinrin nipinlẹ naa ti sọ pe awawi ti ko lẹsẹ nilẹ ati itan aalọ ijapa ni ọkunrin naa n sọ, nitri awọn maa wọ afurasi yii lọ siwaju adajọ ni kootu to n ri sọrọ ọmọde, ibalopọ ati ifiyajẹ abo, to wa niluu Awka, nipinlẹ Anambra, lati le lọọ ro tẹnu rẹ.