Kazeem Aderohunmu
Wọn sọ pe o pẹ ti Charles Ekwe ti maa n fipa ba aburo iyawo ẹ, ọmọ ọdun mẹtala, lo pọ ki ọwọ awọn Sifu Difẹnsi too tẹ ẹ, to si ti n ṣalaye ohun to ri lọbẹ tofi waro ọwọ.
Ni gbogbo asiko ti arun Koronafairọọsi se awọn eeyan mọle, ti ijọba sọ pe ki kaluku jokoo sile wọn gan-an ni ọkunrin ẹni ọdun mejidinlaaadọta yii ti maa n ba aburo iyawo ẹ sun. Ṣugbọn lọjọ kejila, oṣu kẹwaa, ọdun yii, lọwọ tẹ ẹ nile wọn ni Nọmba 1B, Suurulere, Ọjọ, l’Ekoo.
Agbẹnusọ fawọn Sifu Difẹnsi, Bada Kehinde Mary, sọ pe ni gbogbo igba ti ofin konile-gbele tijọba ṣe fi fẹse rinlẹ daadaa ni ẹni-afurasi yii ti n fipa ba ọmọ naa lo pọ, ṣugbọn ti ọmọ naa ko le fọrọ ọhun to aunti rẹ leti.
Ọmọ yii sọ pe, ọkọ aunti oun toun n pe ni daddy yii ti n ṣere buruku pẹlu oun lati ibẹrẹ ọdun yii, oun ko si le ka iye igba to ti ṣere buruku yii pẹlu oun, nitori lọpọ igba lo maa n ki oun mọlẹ ti ile ba ti da. O ni ni kete ti ẹgbọn oun yii ba ti kuro nile lo maa n ṣe kinni fun oun, bẹẹ lo tun maa n ṣe e foun daadaa ninu sọọbu to ti n ta ọja.
O fi kun un pe ọkunrin naa lo tun fi oriṣiiriiṣi fiimu onihooho han oun lori foonu rẹ, to si ki oun nilọ pe lọjọ ti oun ba sọ ọ sita, iku ojiji loun yoo fi pa oun danu.
Ẹgbọn ọmọ naa, Blessing Ekwe, sọ pe ọdun kẹrin ree ti aburo oun yii ti n gbe lọdọ awọn ni kete ti baba ẹ ti ku. Ni nnkan bii ọsẹ mẹta sẹyin lo ni oun fura pe ọmọ naa ko turaka, loun ba fọrọ wa a lẹnu wo, ln laṣiiri fi tu si oun lọwọ pe ọkunrin naa ti ba a laye jẹ jina.
Ọsibitu ni wọn ti fidi ẹ mulẹ pe, o pẹ ti wọn ti n fipa ba a lo pọ.
Charles ti wọn fẹsun kan yii naa ti sọ pe oun ko ba a lopọ, oun kan maa n fọwọ pa a labẹ lasan ni, bẹẹ loun tun maa n fi fidio ibanilopọ han an lori foonu oun.
Ọgbẹni Ayẹni Paul, ọga ẹṣọ ọhun ti sọ pe o di dandan ki ọkunrin ti wọn mu yii foju wina ofin lẹyin tawọn ba ti fa a le ẹka ijọba ti yoo ba a ṣẹjọ lọwọ.
O ye ki ijoba yegi fun okunrin yii ni o.. Alailojuti
I support you @#AkinosunAdekunle