Ọrọ Sunday Igboho da ija Naijiria ati Bẹnnẹ silẹ poo!

YẸMI ADEDEJI

Gbogbo ọgbọn pata ni ijọba apapọ orilẹ-ede yii n ta lati ri i pe nigbẹyin-gbẹyin, ọwọ awọn to Sunday Adeyẹmọ, ẹni ti gbogbo eeyan n pe ni Sunday Igboho. Ohun to wu wọn gan-an ni ki wọn gbe e de Naijiria, ki wọn ba a ṣẹjọ, nitori wọn ti ṣeto ẹjọ naa kalẹ bayii, wọn si ti dẹ okun oriṣiiriṣii silẹ fun un. Bi wọn ba si ri i mu, ẹwọn ọlọjọ pipẹ ni wọn yoo sọ ọ si debii pe yoo ti darugbo kujọkujọ ki wọn too jẹ ko jade. Bakan naa ni wọn n halẹ mọ gbogbo awọn ti wọn jẹ alatilẹyin fun Igboho, wọn n halẹ pe awọn yoo mu awọn naa ti mọle ti awọn ko ba ri Igboho, awọn yoo fi wọn rọpo rẹ, bo tilẹ jẹ pe ohun to wu wọn gan-an ni lati ri ọkunrin naa mu funra rẹ. Bi wọn ko ba ri i mu lọwọ ẹrọ, wọn ko kọ ki wọn ji i gbe lojiji, kawọn ọdaran kan ba wọn gbe e wale lọna ti ko bofin mu, ti wọn yoo si sọ pe awọn naa kan ri i ni Naijiria lojiji ni.

Gbogbo ọgbọn ti wọn n da yii ni ijọba Bẹnnẹ mọ, ṣugbọn wọn ko fẹẹ gba fun Naijiria rara, ọrọ naa si ti fẹẹ dija laarin wọn. Gbogbo agbara ti ijọba Naijiria ni ni wọn fi n halẹ mọ Bẹnnẹ, nitori orilẹ-ede naa ko tobi to Naijiria, bẹẹ ni wọn ko ni ohun amuṣọrọ tabi nnkan ija ti wọn le fi koju Naijiria ti ija ba de, paapaa ju lọ, ọdọ Naijiria ni wọn n wo lati ri i pe awọn ri eto ọrọ aje to dara. O fẹrẹ jẹ pe lẹyin Naijiria, ko tun si ibi ti awọn oniṣowo mọto ti n ko o wọ Afrika to tun to oju-omi ti Kutọnu, ni Bẹnnẹ, mọto to n wọbẹ lojumọ kan ko ṣee fẹnu sọ. Ṣugbọn ki i ṣe orilẹ-ede naa ni wọn ti n ra awọn mọto yii, koda wọn ki i ta ju boya ẹyọ kan ninu ọgọrun-un lọ, ibi ti wọn ti n ra gbogbo mọto ti wọn n ko wa yii, Naijiria nibi ni, fayawọ ni wọn yoo si fi gbe kinni naa wọle lẹyin ti orilẹ-ede Bẹnnẹ ba ti gba owo ẹnubode tiwọn.

Bakan naa ni irẹsi, ọkọ oju omi maa n gunlẹ si orilẹ-ede Bẹnnẹ lojoojumọ aye yii ni, irẹsi ni wọn si n ko to pọ ju lọ. Bẹẹ ni ki i ṣe awọn ara Bẹnnẹ ni wọn n jẹ irẹsi naa ni tootọ, pupọ ninu irẹsi yii, Eko ati Sango-Ọta ni yoo pada ja si, nibẹ lawọn ọmọ Naijiria yoo si ti maa ko o. Bakan naa ni awọn nnkan mi-in loriṣiiriṣii bẹẹ to jẹ Bẹnnẹ ni awọn oniṣowo maa n ko wọn gba, nitori pe Naijiria ti fi ofin de wọn, tabi nitori owo ẹnubode ti Naijiria yoo gba lọwọ awọn ọlọja naa yoo pọ ju gan-an si eyi ti wọn yoo gba lọwọ wọn ni Bẹnnẹ. Nigba ti owo ti wọn yoo gba lọwọ wọn ni Bẹnnẹ yii ko ti to nnkan, to si jẹ ki i nira lati ko ọja naa wọle si Naijiria, ẹnubode Bẹnnẹ yii lawọn oniṣowo Naijiria n ko ọja gba ju lọ, ohun to si jẹ ki iṣẹ fayawọ pọ ni apa ibi yii niyi, to jẹ tọmọde tagba lo n ṣe e, titi dori awọn aṣọbode ti wọn n gbe si ọna Kutọnu.

Ọrọ naa ye ijọba Naijiria daadaa, pe Naijiria ni Bẹnnẹ fi n pawo, nitori gbogbo ọja ti wọn n ko wọ Kutọnu, Eko tabi Sango lo n bọ, ọna fayawọ ni yoo si gba wọle. Ṣugbọn ijọba yii fi wọn silẹ, iyẹn ijọba Naijiria, wọn yi oju si ẹgbẹ kan, ki orilẹ-ede Bẹnnẹ le maa jẹ anfaani yii, ati pe awọn ti wọn n ṣejọba Bẹnnẹ yii ki i fi awọn olori ijọba Naijiria silẹ nigba kan. Igba kan tiẹ wa, laye olori orilẹ-ede Bẹnnẹ to ṣẹṣẹ gbejọba silẹ, Boni Yayi, to jẹ niṣe ni ọkunrin naa sọ pe ki Naijiria kuku sọ orilẹ-ede awọn di ọkan ninu awọn ipinlẹ rẹ, nitori Naijiria ni baba awọn. Laye Obasanjọ ni o, ti ọkunrin olori ijọba Bẹnnẹ naa ki i wọn ni Naijiria rara, nitori nibi ni ọrọ aje wọn wa. Lati igba ti Buhari ti gbajọba yii ṣaa ni nnkan ti yipada diẹ loju ọna naa, ti wọn ni awọn n gbogun ti awọn onifayawọ, ti wọn si ti ẹnubode Naijiria ati Bẹnnẹ pa, ti ko si ọja to le wọle.

Loootọ ni ijọba Buhari lawọn n gbogun ti fayawọ, ati pe nitori ẹ lawọn sẹ ti ẹnubode pa, ṣugbọn ọrọ naa le ju bẹẹ lọ, nitori ẹnubode Eko ati tipinlẹ Ogun ni wọn ti pa ju, awọn ẹnubode to ja si Bẹnnẹ lati ilẹ Hausa ṣi n ba iṣẹ wọn lọ pase-pase, ti ko si kọsitọọmu to n mu wọn. Sibẹ naa, eyi ko ta awọn ijọba Bẹnnẹ lara, nitori Eko, Ogun lowo wa, ibẹ ni wọn ti n ko ọja to pọ wọle ju lọ ti wọn si n pa owo rẹpẹtẹ, owo ti wọn n pa ni awọn ọna ilẹ Hausa yii ko to ida mẹwaa ohun ti wọn yoo pa ni Eko ati Sango. Eleyii gan-an lo da bii pe ijọba Naijiria naa ko fẹ, nitori wọn ko fẹ ariwo ti awọn eeyan n pa pe Eko tabi ilẹ Yoruba ni owo Naijiria ti n wọle ju lọ, pe ko si owo kan to n wọle lati ilẹ Hausa. Ariwo pe ko si owo to n wọle lati ilẹ Hausa yii, ati pe ilẹ Yoruba lowo ti n wọle ju yii, wa lara ohun to fa a ti wọn fi ti ẹnubode yii pa, ti wọn ko si ṣi i silẹ lati ọjọ naa wa.

Lati inu oṣu kẹjọ, ọdun 2019, iyẹn ọdun mẹta bayii geere, ni ijọba Naijiria ti ti ẹnubode wọn pẹlu awọn ara Bẹnnẹ yii, ti awọn tọhun si n ja fitafita lati ri i pe wọn ṣi ẹnubode naa, nitori wọn ni wọn fẹẹ pa eto ọrọ aje awọn ni pẹlu ẹnubode ti Naijiria ti pa. Awọn ijọba ati awọn alagbara ni Bẹnnẹ ti wa si Naijiria lati ba awọn olori ijọba tiwa nibi ṣepade, ti wọn si n ṣalaye fun wọn pe awọn ko faaye gba fayawọ, nitori ko si ọmọ orilẹ-ede awọn to n ṣe fayawọ yii, pe awọn ọmọ Naijiria lonifayawọ, bi ijọba ba si le da awọn ọmọ Naijiria lọwọ kọ, ti wọn ri i pe awọn kọsitọọmu wọn ki i gba owo abẹtẹlẹ lọwọ onifayawọ, o daju pe ohun gbogbo yoo lọ bo ṣe yẹ ko lọ. Wọn ni bo ba jẹ ti ọdọ awọn ni, ko si oṣiṣẹ awọn ti yoo gbowo ẹyin, ko si ọmọ orilẹ-ede naa kan ti yoo ṣe fayawọ, bẹẹ ni ko si kọsitọọmu awọn ti yoo gbowo lọwọ onifayawọ kan.

Ohun ti Naijiria ati Bẹnnẹ n fa mọ ara wọn lọwọ ree ko too di pe ọrọ Sunday Igboho yi wọ ọ, to si kuku waa da bii pe Ọlọrun ba ijọba Naijiria ṣe e. Ọlọrun ba wọn ṣe e nitori gbogbo ohun ti wọn ti ro ni pe ohun yoowu ti awọn ba fẹ ni Bẹnnẹ yoo ṣe, wọn yoo mu Sunday Igboho bi wọn ti ri i yii, wọn ko si ni i jẹ ki ilẹ mọ ti wọn yoo fi ju u loko pada si Naijiria, ki ọrọ si too di ariwo rara, yoo ti wa lọdọ awọn DSS, nibi ti yoo ti maa rojọ ẹnu rẹ. Ohun tijọba Naijiria n reti ree, nitori rẹ si ni awọn DSS ko ṣe fi awọn ti wọn ko nile Igboho silẹ ki wọn jade, nitori ki wọn le ri wọn ko pa mọ, ki wọn ma tun ṣẹṣẹ maa wa wọn kiri nigba ti ọwọ wọn ba tẹ Igboho. Wọn ti ro pe kinni naa yoo ya kiakia, nitori ewurẹ ko lori ti yoo fi ba agbo kan, ki i ṣe ni Bẹnnẹ ni wọn yoo ti di awọn lọwọ lati ṣe ohun ti awọn ba fẹẹ ṣe ni Naijiria.

Ijọba Naijiria mọ pẹ iru nnkan bayii ko bofin agbaye mu, pe ki orilẹ-ede kan deede mu ẹni kan ti wọn n wa niluu rẹ, ki wọn si ju u loko sile lai wadii ọrọ naa rara, ati lai ṣe gbogbo ohun to yẹ ki wọn ṣe. Ijọba Naijiria mọ pe ti awọn ba gbe ọrọ Igboho gba ti ọna ofin, ọdun kan si meji bayii, awọn ṣi wa lẹnu ẹ, iyẹn ni wọn ko ṣe fẹẹ gbe e gba ọna ofin yii, wọn kan fẹ ko jẹ bi wọn ti mu Igboho yii, wọn da a pada fawọn ki ẹnikẹni tilẹ too mọ pe wọn ti mu un rara. Bi wọn ba mu un lojiji bẹẹ ti wọn da a pada wale, Naijiria mọ bi wọn yoo ti ṣeto naa ti wọn yoo fi gba orilẹ-ede Bẹnnẹ lọwọ ariwo, wọn tilẹ le ni ki i ṣe ibẹ lawọn ti mu un. Ṣugbọn ijọba Bẹnnẹ mọ pe awọn orilẹ-ede alagbara lagbaaye ko fẹ bẹẹ, ọrọ naa si le pada waa mu wọn lomi lẹyin ti wọn ba ti wadii, ti wọn si ri i pe ni Bẹnnẹ ni wọn ti mu un, ti wọn ko si tẹle ofin to yẹ.

Ọrọ naa ka Naijiria lara, o dun wọn pupọ pe ọrọ ti ko yẹ kawọn ara ile keji gbọ, ohun ti ko yẹ ki o di ariwo rara, awọn eeyan naa ti sọ ọ di nnkan ariwo, wọn si ti pe gbogbo agbaye le awọn lori. Nitori ẹ ni wọn ṣe sa sẹyin, ti wọn ṣe bii ẹni pe ọrọ Igboho ko kan wọn rara. Wọn ko fẹ ohun ti yoo jẹ ki aye ri wọn bii arufin, ati bii ijọba ika to n le alaiṣẹ kaakiri. Nitori ẹ ni wọn ko ṣe de ile-ẹjọ tabi da si ẹjọ to n lọ, ti wọn ko si ti i fi ọrọ kan si gbangba lori ẹjọ naa tabi itimọle ti wọn fi Igboho si nibẹ. Ohun ti wọn si n ro ni pe bo ti wu ki ọrọ naa ri, ijọba Bẹnnẹ yoo ṣe ẹtọ, ẹtọ ti wọn si n reti lati ọdọ wọn naa ni ki wọn da Igboho pada sile lẹyin ti wọn ba ti gbọ ẹjọ ẹ tan, ki gbogbo aye le ri i pe ki i ṣe awọn lawọn lọọ gbe Igboho wa o, ilu oniluu to lọ ni wọn ti ka ẹsun si i lẹsẹ, nibẹ ni wọn si ti fi i ranṣẹ sile, ki i ṣe awọn lawọn lọọ mu un.

Ki eleyii le ṣee ṣe, ati ki wọn le dẹru ba awọn ijọba Bẹnnẹ, ni gbara ti ọrọ yii ṣẹlẹ, ti wọn ti ṣeto ẹronpileeni to le gbe ọkunrin naa laarin oru ti iyẹn ja si pabo, wọn ni ki aṣoju Naijiria tuntun ni Bẹnnẹ lọọ kọ iwe ‘ẹ kuule’ ẹ fun olori orilẹ-ede naa, ki wọn le foju ri ara wọn. Buratai, olori awọn ṣọja tẹlẹ ni Naijiria ni aṣoju orilẹ-ede yii ni Bẹnnẹ bayii, bo ṣe kuro ninu iṣẹ ṣọja, ko pe oṣu kan ti wọn gbe iṣẹ tuntun naa fun un, wọn ko tiẹ sinmi rara.  Ṣugbọn lati igba ti wọn ti gbe e lọ, ko ti i jokoo si Bẹnnẹ yii, ẹẹkan abi ẹẹmeji lo debẹ, to ni kawọn to wa nibẹ tẹlẹ maa ba iṣẹ lọ, bo ba ya, oun yoo yọju si wọn lẹyin ti oun ba ti sinmi daadaa. Ṣugbọn o ti bẹrẹ si i gbowo oṣu o, bẹẹ lo n gba gbogbo ẹtọ to tọ si i gẹgẹ bii aṣoju Naijiria ni Bẹnnẹ, bo tilẹ jẹ pe ko ti i lọ sọhun-un ko maa gbe. Nibi to ti n fẹsẹ palẹ bayii, to n gbadun owo ijọba, nibẹ lọrọ Igboho ti de.

Ọrọ Igboho yii lo jẹ ko sa janna janna de, ti wọn si sare lọọ ko iwe rẹ jade, ti wọn ni ko waa lọọ ri olori orilẹ-ede Bẹnnẹ lati fi ara han an pe oun ni aṣoju orilẹ-ede Naijiria tuntun lọdọ wọn. N lo ba si lọọ ba a. Loootọ ọkunrin naa ko wi kinni kan nibẹ, tabi sọrọ to jẹ mọ ti Igboho, ohun ti ijọba Naijiria ṣe ni lati fi Burutai halẹ mọ ijọba Bẹnnẹ, ki wọn le mọ pe alagbara ọkunrin kan, olori awọn ṣọja tẹlẹ, laṣoju Naijiria lọdọ awọn, ati pe ko si ohun ti awọn fẹ ti ọkunrin naa ko le gba fawọn, bi awọn naa ba ti ṣe ohun to yẹ ni ṣiṣe. Iṣẹ akọkọ ti wọn n reti ni ṣiṣe lati ọdọ ijọba Bẹnnẹ naa ni ki wọn fa Sunday Igboho le wọn lọwọ, lọna ti yoo fi da bii pe awọn Bẹnnẹ ni wọn ṣe Igboho pa, ki i ṣe ijọba Naijiria rara. O jọ pe wọn ti fi ara sọ fun wọn nibẹ paapaa pe bi wọn ba jẹ ki Igboho lọ mọ wọn lọwọ, awọn ko ni i ṣi bọda wọn, awọn yoo ti kinni naa pa titi aye ni.

Bi ijọba Bẹnnẹ ko ba fi le gbe Igboho fun wọn bayii, ohun ti awọn ijọba Naijiria n reti ni pe ki Bẹnnẹ ka ẹsun awuruju si Igboho lẹsẹ, ki wọn si ju u si ẹwọn bii ogun tabi ọgbọn ọdun lọdọ wọn, ko maa ṣe ẹwọn naa lọ nibẹ. Ohun tawọn ijọba Naijiria n ro ni pe ka lọṣọ mọdii, ka lọdii maṣọ, bi idi ko ba ṣaa ti gbofo, ọkan naa ni. Bi wọn ko ba ni i ri i gba ni Naijiria, ti ijọba Bẹnnẹ ko ba le gbe e fawọn, ti wọn ba ti sọ ọ sẹwọn lọhun-un, ṣebi ki Igboho ṣaa ti ma si laarin ilu ni, ko ma ri aaye maa rin kiri, ko ma sọna ti yoo fi pada si Naijiria lati maa wa ko awọn ero jọ pe awọn n fẹ Yoruba Nation, ko sohun ti awọn tun n fẹ ju bẹẹ lọ. Bijọba ilẹ Bẹnnẹ ba ti le ṣeto ẹwọn gidi fun un, ti ẹwọn naa jẹ ti ọlọjọ-pipẹ, ko si wahala kan nibẹ mọ, awọn yoo mọ pe awọn ara Bẹnnẹ yii o, ọrẹ gidi ni wọn n ba awọn ṣe, nigba naa lawọn yoo tun ọrọ ẹnubode wọn yẹwo.

Ṣugbọn eto ti ijọba Bẹnnẹ ni fun Sunday Igboho yatọ pata si ohun ti awọn eeyan ni Naijiria n fẹ. Awọn funra wọn ti ri i pe Igboho ki i ṣe ẹlẹṣẹ, ko ṣẹ sofin Naijiria kankan, bẹẹ ni ko ṣẹ si ofin ọdọ awọn naa, nitori o ni iwe irinna, o si le wọ ọdọ awọn nigba to ba fẹ. Wọn mọ pe Naijiria kan fẹẹ mu ọkunrin naa lati lọọ fi i pamọ ni, tabi ki wọn ṣe e leṣe ninu ọgba ẹwọn ti wọn ba fi i si. Nitori eyi, ijọba Bẹnnẹ ko fẹẹ fa Sunday Igboho le awọn ijọba Naijiria lọwọ, wọn mọ pe gbogbo oju aye lo wa lara awọn, bẹẹ ni wọn ko fẹẹ sọ ara wọn lẹnu, paapaa lori ọrọ ti ki i ṣe tiwọn tabi ti eeyan wọn. Yatọ si eyi pẹlu, awọn eeyan nla nla ilẹ Bẹnnẹ ko jẹ ki awọn ijọba wọn yii gbadun, nitori awọn ọba Yoruba, awọn oloṣelu Yoruba to jẹ ibẹ ni wọn wa, n pariwo, ariwo naa si fẹrẹ di ijọba wọn leti, pe Igboho ko ṣẹ ijọba Naijiria, ki wọn ma fiya kankan jẹ ẹ.

Awọn eeyan yii naa lọọ ri Aarẹ wọn nibẹ, iyẹn Aarẹ Patrice Talon, bẹẹ ni wọn gba awọn lọọya nla nla ti wọn n ba awọn minista ati adajọ sọrọ lati ṣalaye bi ọrọ ti jẹ, ohun ti ijọba naa si ri ni pe loootọ ni Igboho ko ṣẹ, wọn fẹẹ fiya jẹ ẹ lasan ni. Awọn ijọba Naijiria ko dakẹ o, wọn kan n fi ọgbọn ṣe ohun ti wọn n ṣe ni. Wọn fẹẹ mọ idi ti agbara Igboho yii fi to bayii, nigba naa ni wọn mọ pe ẹni ti wọn n pe ni Olulana, iyẹn Ọjọgbọn Banji Akintoye funra ẹ wa ni Bẹnnẹ, ibẹ lo ko lọ lati igba ti ọrọ Igboho yii ti bẹrẹ. Nijọba Naijiria ba bẹrẹ ihalẹ pe awọn yoo mu baba naa nibi ti awọn ba ti ri i. Niṣe ni baba yii jade, to ni oun ko sa lọ, oun wa ni Bẹnnẹ, boun ba si ti pari ọrọ Igboho ni oun n bọ nile, ẹni to ba fẹẹ mu oun ko maa reti oun lẹyin tawọn ba ti yanju ọrọ Sunday Igboho. Bẹẹ loootọ, lara awọn ti wọn n ṣalaye ọrọ fun ijọba Bẹnnẹ ni baba naa n ṣe.

Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ naa ti lọ si Kutọnu. Loootọ, iyawo ọrẹ rẹ to ku, iyẹn, olori orilẹ-ede Bẹnnẹ tẹlẹ, aarẹ Soglo, lo tori ẹ lọ lati lọọ ba ọrẹ rẹ kẹdun, sibẹ, baba naa de ọdọ aarẹ tuntun ni Bẹnnẹ, ko si si tabi ṣugbọn nibẹ, ọrọ Sunday Igboho lo ba lọ. Ijọba Naijiria tilẹ nigbagbọ pe Ọbasanjọ kan fi ọrọ iku iyawo ọrẹ ẹ boju ni, nitori Igboho lo ṣe lọ si Bẹnnẹ, eleyii si tun da ibẹru si wọn lọkan, nitori wọn ko mọ ohun to ba Aarẹ Bẹnnẹ sọ. Pelu gbogbo eyi, ko si bi ijọba Bẹnnẹ ṣe le deede fiya jẹ Sunday Igboho tabi ki wọn da a pada fun ijọba Naijiria. Ohun ti wọn fẹẹ ṣe ni lati wa ẹsun kerekere kan de mọ ọn lẹsẹ ti wọn yoo fi ti i mọle nibẹ, ti yoo wa lọdọ wọn titi ti ijọba Buari yii yoo fi kogba wọle, ti wọn yoo si fi i silẹ ko maa lọ. Wọn ni bi awọn ba fi i silẹ bayii, ijọba Naijiria le ji i gbe, tabi ki wọn pa a mọ awọn lọwọ, wọn yoo si ni Bẹnnẹ lo pa a.

Eyi ti Bẹnnẹ fẹẹ ṣe yii ko tẹ wọn lọrun ni Naijiria nibi, ijọba Naijiria ti bẹrẹ si i binu gan-an. Wọn ti n dunkooko mọ wọn ni Bẹnnẹ, nitori wọn n ran awọn eeyan si wọn labẹlẹ lati maa halẹ mọ wọn pe oju wọn yoo ri mabo ti wọn ba ṣe ọrọ Sunday Igboho yii yọboyọbọ, eyi ti awọn si n wi yii ni bi wọn ba jẹ ki Igboho bọ, ti wọn ko fi i ranṣẹ si Naijiria, ti wọn ko si sọ ọ sẹwọn ọlọdun gbọgbọrọ. Ko jọ pe orilẹ-ede Bẹnnẹ yoo ṣe eyikeyii ninu ọrọ mejeeji yii, pẹlu gbogbo ariwo to n lọ ni Bẹnnẹ, ni Naijiria, ati kaakiri agbaye. O jọ pe ijọba Bẹnnẹ ti pinnu pe ohun ti Naijiria ba fẹẹ ṣe ki wọn ṣe e, ara to ba wu wọn ki wọn da, awọn o ni ẹwọn ọlọjọ gbọgbọrọ ti awọn fẹẹ fi Igboho si, awọn o si ṣetan lati da a pada, ki Naijiria ma halẹ kankan ma’wọn.

Ohun ti ko sẹni to ti i le sọ bayii ni boya Bẹnnẹ yoo ba Naijiria fa ọrọ naa kanlẹ bayii, abi igba kan n bọ ti wọn yoo sọrẹnda, ti wọn yoo si ṣe ohun ti Naijiria ba fẹ ki wọn ṣe. Ṣugbọn bi nnkan ti wa bayii, ọrọ Igboho yii, ijọba naa ni yoo da silẹ laarin Naijiria ati Bẹnnẹ, nigbẹyin si ree, ẹni kan ni yoo jare, ẹni kan ni yoo jẹbi. Ẹ jẹ ka maa ba a bọ na o!

Leave a Reply