Ọrọ to yẹ ki Tunde ba ọrẹ rẹ tuntun sọ

Nigba ti mo kọ ọrọ lori Tunde (Pasito Bakare), jade lọsẹ to kọja, oriṣiiriṣii iwe ni mo n gba lori aago, diẹ ninu awọn atẹjiṣẹ naa si ba mi lẹru. Ohun to jẹ ko ba mi lẹru ni pe awọn eeyan wa ki i fi ara balẹ gbọ ọrọ, nigba ti o ba gbe ironu gidi kalẹ, ti o ro pe o ti ṣalaye bi ọrọ ti jẹ gan-an fun wọn, ibi ti o ko ro ni wọn yoo gbe ọrọ naa si patapata, awọn ọrọ ti wọn yoo si maa sọ, yoo yatọ si ohun ti iwọ n sọ lẹnu. Awọn yii ni bi Tunde ba sọrọ bayii nipa Bọla, to ni ka gbagbe nipa itan bi wọn ti bi i ati awọn to bi i, pe ka ṣe bi Tunde ti wi yẹn, nitori ìṣẹ́ lo maa n mu ki agbalagba pa itan buruku. Ṣugbọn ẹni kan beere ọrọ pataki kan lọwọ mi, mo si fẹẹ fesi si ọrọ naa ki n too maa ba awọn nnkan mi-in lọ. Ọrẹ mi yii ni ṣe to ba di asiko ibo to n bo, ti wọn ba fa Bọla to jẹ ọmọ Yoruba silẹ lati du ipo aarẹ, ṣe n ko ni i dibo fun un ni, nitori mo koriira rẹ.

Akọkọ ni pe mo ti sọ ọ ni igba aimọye nibi yii, n ko koriira Bọla. Ohun to n mu wa yapa sira wa ko ju ọrọ Yoruba lọ. Bọla atawọn tiẹ fẹran lati fi orukọ Yoruba jẹun, lati fi orukọ Yoruba gba ipo, ati lati fi orukọ Yoruba gba owo to ba jade lati Abuja, ki wọn si lo gbogbo rẹ fun ara wọn nikan lai fun awọn Yoruba ti wọn forukọ wọn gba awọn nnkan wọnyi. Eleyii ko si ninu awọn ilana temi. Bi Yoruba yoo ṣe dara lapapọ lo wa lọkan temi, n ko si ronu iye ti mo le ri gba, tabi owo ti mo fẹẹ ri nidii awọn ohun ti mo ba ṣe fun Yoruba. Emi n ṣe temi fun iran yii ati iran awọn ọmọ wa to n bọ lọla ni. Awọn iwa ti awọn Bọla n tori oṣelu hu ni ko le jẹ ka ṣọrẹ, oṣelu ti ko ba ti ni i ṣe pẹlu ilọsiwaju awọn eeyan wa lapapọ, emi o fara mọ ọn. Ki i ṣe ka ri ẹni kan ka fun un lowo nla kan, tabi ka ri wọn lode ijo ka ko owo fun wọn, ni wọn n pe ni oore ṣiṣe funluu. Ipo ti Bọla wa ni Naijiria bayii, oore to ba fẹẹ ṣe, oore to yẹ ko ran gbogbo ilẹ Yoruba lọwọ ni.

Awọn ibi yii ni ọrọ wa ti maa n yatọ sira, ti mo si maa n binu nigba mi-in nitori awọn ohun ti mo mọ nipa Bọla ati awọn eeyan ẹ. Ṣugbọn bo ba jẹ nigbẹyin, ẹgbẹ oṣelu wọn, tabi ẹgbẹ oṣelu mi-in, ko ri ẹlomiiran fa kalẹ ju oun Bọla lọ, a jẹ pe ko si ohun ti mo le ṣe, oun naa ni ma a dibo mi fun, koda mo le sọ fawọn eeyan ki wọn dibo fun un. Eyi ki i ṣe pe mo nigbagbọ pe yoo ṣe Yoruba daadaa bo ba debẹ, ṣugbọn nitori pe tirẹ yoo yatọ si tawọn Fulani amunnipa to wa nibẹ bayii ni, ati pe ayipada yoo de yatọ si kawọn Hausa-Fulani nikan maa se ijọba lọ. Bi a ba ti yọwọ iyẹn kuro, ko si nnkan kan ti yoo jẹ ki n dibo fun Bọla. Bi ẹgbẹ oselu mi-in ba le fa ọmọ Yoruba mi-in kalẹ, ẹni ti ma a ba lọ niyẹn.

Ohun ti n oo fi ṣe bẹẹ ni pe oṣelu ti awọn Bọla n ṣe ki i ṣe oṣelu to n ran ilẹ Yoruba lọwọ, oṣelu to n pin ilẹ Yoruba yẹbẹyẹbẹ ni, nitori bi awọn yoo ṣe pa awọn agba kan saye tabi ti wọn aa pa wọn sọrun, ki wọn le maa ri ohun gbogbo to ba jẹ ti ilẹ Yoruba ko sapo ara wọn nikan lo wa lọkan won. To ba jẹ pe awọn ọrọ̀ to tọ si Yoruba to n ti Abuja wa, tabi awọn owo-ori ti awọn eeyan wa n san yii, to ba jẹ pe oṣelu awọn Bọla faaye gba ki wọn lo iru owo bẹẹ fun idagbasoke awọn eeyan wa ni, koda ko ni ki awọn agbaagba wọnyi lọọ binu ku, mo le ma da si i o, nitori bi a ba tan an wo daadaa, awa ti a n pe ara wa ni agba yii naa yoo ni tiwa lọwọ, bi ko ju bi ko ju, agidi buruku to wa ninu wa. Ṣugbọn a ko le fi agidi we ibalujẹ, tabi ẹni to n fa awọn eeyan rẹ sẹyin nitori ki oun le ga, ki wọn le maa pe e ni baba. Aṣa ati awọn alalẹ Yoruba ko fẹ iru iyẹn.

Mo binu nigba ti wọn n sọ pe ki a dibo fun Buhari lọjọsi nitori Ọṣinbajo, ti wọn ni oun ni igbakeji, Yoruba yoo le wa nipo igbakeji bi wọn ba wọle. Mo sọ fawọn ti wọn waa ba mi nigba naa pe bi awọn eeyan yii ba gbajọba tan, ti Ọsinbajo ti wọn n sọrọ ẹ yii ba fi ori mẹyin, wọn aa maa lo o bii bọibọi, ọmọ ọdọ lasan ni wọn o maa fi i ṣe. Ṣugbọn ti ko ba fi ori mẹyin, to ba fẹẹ maa pe ara rẹ ni igbakeji Buhari, wọn aa pa a ti bi aṣọ to gbo, debii pe ipo to wa naa, ko ni i fi wulo kan fun Yoruba, koda ko ni i wulo fẹnikan, nitori iṣẹ buruku lasan ni aa maa fun un ṣe. Awọn ti mo ba sọrọ naa yinmu si mi nipaakọ, bo tilẹ jẹ pe wọn ko sọrọ ti ko daa loju mi. Bẹẹ mo mọ, mo si gbọ pe inu wọn ko dun si ohun ti mo sọ, wọn ni ọga lọọya ni Oṣinbajo, ọmọwe si ni, o mọ bo ṣe maa ṣe e. Ọlọrun ṣe e, gbogbo wa naa la ti foju ri i bo ti ṣe e si.

Bo ba ṣe pe ipo kin-in-ni ni Yoruba fẹẹ wa, to jẹ ọmọ Yoruba ni yoo di ipo aarẹ mu funra ẹ, iyẹn yatọ gan-an ni, ko si sohun ti o ni i jẹ ki n dibo fun Bọla nitori ẹ, bo ba jẹ oun ni ẹgbẹ rẹ fa kalẹ. Amọ bi ọmọ Yoruba mi-in ba dide ninu ẹgbẹ mi-in, ko sohun ti ẹnikan le ba mi sọ, oun ni n o ba lọ, iyẹn ọmọ Yoruba mi-in yii. Idi ni pe yatọ si ede Eko ti Bọla n sọ lenu, ko fi ara rẹ han bii Yoruba, nitori ki i gbeja Yoruba nibi kan, bẹẹ ni ki i sọrọ Yoruba to ba ti wa laarin awọn ara ẹ nilẹ Hausa. Awọn kan ti sọ fun mi pe ki n ma ronu bẹẹ, o n tan wọn ni, o fẹẹ mu ọbọ, o n ṣe bii ọbọ ni. Ṣugbọn emi mọ pe to ba jẹ Bọla ti mo mọ yii ni, ki i ṣe pe o n huwa bẹẹ lati mu ọbọ kankan o, iwa rẹ to n hu lati ilẹ niyẹn, o si ti sọ ọ loju mi laimọye igba pe oun ko ṣe oṣelu Yoruba, oun o ṣe aṣaaju Yoruba, oloṣelu ati aṣaaju Naijiria loun. Tori bẹẹ, gbogbo ohun to ba n ṣe, ilẹ Hausa ki i kuro lọkan rẹ.

Ohun ti n ko ṣe ni i dibo fun un bi Yoruba mi-in ba yọju ko ju ọrọ ti a n fa mọ ara wa lẹnu lọsẹ to kọja lọ. Loootọ ija naa ti n pari, Tunde ti n ba awọn agba to bu sọrọ, o si ti tọrọ aforiji nibi ti wọn sọ fun un pe o ti sọ aṣisọ, sibẹ awọn kinni kan wa ti mo fẹẹ sọ ki ẹyin naa gbọ. Akọkọ ni pe ko si bi aye eeyan ti le buru to ti yoo sọ pe baba oun tabi iya oun kọ lo bi oun. Ipo yoowu ti iru baba bẹẹ ba wa, ipo yoowu ti iru iya bẹẹ ba wa, Ọlọrun funra rẹ a maa gbe ọmọ ga lati fi san awọn obi ni ẹsan iya to jẹ wọn, bi ọmọ kan ba waa kọyin si awọn obi rẹ yii, iru ọmọ bẹẹ le ri ibinu Ọlọrun, bo ti wu ko ga to. Eyi ni Yoruba ko fi ni aponle fun ọmọ to ba tapa si obi ẹ. Bọla hu iru awọn iwa yii, gbogbo aye si n pariwo pe ko daa. Ṣugbọn ko jẹwọ titi ti Tunde fi waa tu aṣiri ọrọ naa jade. Awọn ti wọn n ba Tunde rin mọ ile ẹ, won mọ iya ẹ, wọn mọ baba ẹ, ki lo de ti Tunde ko waa sọ bẹẹ fun Bọla pe ko jẹwọ ohun yoowu to ba ṣẹlẹ si i, tabi ko sọ fawọn agbaagba yii ni kọrọ.

Lọna keji, eeyan ki i dagba kọja ilu ti wọn ba ti bi i. Nibo ni wọn ti bi Bọla gan-an, ibo si ni agboole wọn. Ko si ohun to buru ninu ki eeyan sọ eyi naa sita fawọn to ba yẹ ki wọn mọ. Bẹẹ ni ko si itiju kan nibẹ rara. Ṣugbọn nigba ti ọrọ foju han gedegbe, ti ẹni to ni ọrọ wa n sọ pe ko ri bẹẹ, titi ti to fi waa di pe Tunde lo la ọrọ mọlẹ pe Bọla ki i ṣe ọmọ Eko. Ki lo de ti Tunde ko sọ fun un pe ko ṣalaye ibi ti wọn ti bi i, ko si lọ sibẹ lati ki awọn eeyan ibẹ, ko si ilu ti inu rẹ ko ni i dun pe ibẹ n wọn ti bi iru Bọla. Bẹẹ ni ko sohun to n fẹ l’Ekoo ti ko le ri gba, nigba to jẹ o ti pẹ nibẹ, ti ofin si faaye gba ẹnikẹni to ba ti lo to ogun ọdun nibi kan lati du ipo yoowu to ba fẹ lati ibẹ. Gbogbo awọn nnkan wọnyi ni ọpọ eeyan fẹ ko ti ẹnu Bọla funra ẹ jade. Bo ba ti ṣalaye awọn ọrọ yii, ko ni i si iṣoro kankan fun un mọ, ẹni kan ko si ni i ni ohun ti yoo fi halẹ mọ ọn. Ki Tunde sọ eleyii fun un nigbakigba ti wọn ba rira. Ọrọ mi ko ju bẹẹ lọ mọ lori ẹ.

Leave a Reply